Bi awọn fayawọ ko ba jawọ awa naa ko nii gba - Ọga aṣọbode - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 17 May 2022

Bi awọn fayawọ ko ba jawọ awa naa ko nii gba - Ọga aṣọbode


      


Ọga awọn ẹsọ aṣọbode tipinlẹ Ogun, Bamidele Makinde tun ti sọ pe gbogbo ọna lawọn yoo maa gba lati ri pe awọn to n ṣe fayawọ dinku patapata ati pe bi wọn ba sọ pe awọn ko nii fiṣẹ naa silc, awọn naa ko ni bawọn mu ni ọwọ ere.

Ọkunrin naa sọrọ yii lonii, lakooko to n ṣe ipade pẹlu awọn oniroyin, ni oluuleṣẹ wọn to wa ni Idi- Iroko, nipinlẹ Ogun, nibi to ti n sagbekalẹ awọn aṣeyọri ti wọn ṣe ninu oṣu kẹrin, ọdun yii.

Ọga agba naa sọ pe ọkọ oju omi, oni ẹnijnni mọkan dinlogun ati tirela mẹjọ, to kun fun apo irẹsi lawọn ri gba lọwọ awọn to n ṣe fayawọ.

O sọ pe ọkọ oju omi ẹnjinni ọhun lo jẹ pe marun-un jẹ tuntun nigba ti mẹrinla yooku si jẹ ẹyọm ẹyọ, ti owo ẹ si to miliọnu mẹtadinlogun abọ naira, lawọn ri gba ninu igbo lẹnu aala ilẹ wa, ṣugbon tawọn to ko fẹẹ ko irinṣẹ ọhun wọlu fẹsẹ fẹẹ nigba ti wọn rawọn ẹṣọ aṣobode.

O fikun ọrọ ẹ pe laarin oṣu kẹrin, gbogbo owo tawọn ko ri ko jọ ninu ọja gbanjo tawọn ta fẹẹ miliọnu meje naira, lawọn agbegbe kan to fi de orileede Benin.

 

Bakan naa lo tun tẹnumọ pe ẹnubode ti wọn ṣi gba ki wọn ko awọn gidi wọle ati jade. Bẹẹ lo sọ pe ẹgbẹrun mẹrin ati ẹgbẹta le mẹta ni apo irẹsi tawọn ri gba lọwọ awọn fayawọ ọhun.

 

 

O waa mu dawọn araalu loju pe niwọngba ti wọn ti ṣi ẹnubode bayii ni Idiroko, owo ti wọn n pa wọle yoo tubọ lọọ soke si.

 

Bamidele wa rọ awọn araalu paapaa julọ awọn onifayawọ lati ma ṣe ro pe ṣiṣi ti wọn ṣi ẹnubode silẹ yoo tubọ fawọn laaye lati ma ko ẹru ofin wọle, o ni ẹnikẹni tọwọ ba tẹ ni ijiya wa fun labẹ ofin.

 

Bẹẹ lo tun wa gboṣuba fawọn ọmọọṣẹ atawọn araalu bi wọn ṣe n jẹ ki agbọye wa laarin wọn.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages