Deborah Samuel; Asiko to lati fopin si ifẹmi sofo lorileede yii-Samuel Adeyẹmi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 15 May 2022

Deborah Samuel; Asiko to lati fopin si ifẹmi sofo lorileede yii-Samuel Adeyẹmi


 

Dokita Samuel Adeyẹmi, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Action Alliiance, AA,  nipinlẹ Ogun, ti sọ pe akoko ti waa to bayii lati fopin si fifi ẹmi awọn eeyan ṣofo lorileede yii, ki a si wa ọna abayọ.

 

Ọkunrin yii sọrọ ọhun lakooko to n fi aidunnu ẹ han lori bi wọn ṣe da ẹmi Deboran Samuel legbodo, nileewe awọn olukọni Sheu Shagari, to wa ni Ṣokoto, pẹlu ẹsun ti wọn fi kan an pe o sọrọ odi si Anọbi

 

Oludije naa sọ pe pe iwa tawọn ti wọn ṣiṣẹ ibi ọhun naa hu buru jai, o waa rọ ijọba lati ṣawari iru awọn ti huwa naa ki wọn si fi wọn jofin fawọn eeyan mii.

 

Samuel Adeyẹmi tun ṣalaye siwaju pe ‘ Bi wọn ṣe da ẹmi akẹkọọbinrin Deborah Samuel legbodo lori ọrọ ẹsin jẹ nnkan ti ko ṣe e tẹwọgba lorileede yii, ohun aburu si ni pẹlu. Nnkan to si jẹ ki iru nnkan bẹẹ maa tẹsiwaju ni pe ko si idajọ ododo fawọn ti wọn ti ṣe iru nnkan bẹẹ sẹyin’’

 

O sọ pe itajẹsilẹ ti n pọju lorileede yii lori ọrọ ẹlẹsin de, igba kan lo ni wọn da ẹmi obinrin kan legbodo niluu Abuja, nibi to ti n waasu ọrọ Ọlọrun laaarọ kutu.

 

Ibeere ẹ ni pe Njẹ titi di akoko yii, awọn ti wọn ṣiṣẹ ibi naa, ṣe wọn ri wọn mu? Tabi foju wọn bale-ẹjọ ati pe ṣe wọn jiya lori iwa ti wọn hu naa?

 

O waa sọ pe iku Deborah Samuel, ko gbọdọ lọ lasan, gbogbo awọn ti wọn ṣiṣẹ ọhun ni wọn gbọdọ mu ki wọn si foju bale ẹjọ, ki idajọ ododo si waye pẹlu.

 

Oludije Gomina naa wa ba awọn ẹbi ọmọ naa kẹdun, pẹlu adura pe ki Ọlọrun tu awọn ẹbi ẹ ninu.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages