Ṣẹgun Ṣowunmi fi aidunnu ẹ han lori bi wọn ṣe pa Deborah Samuel nipakupa - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 13 May 2022

Ṣẹgun Ṣowunmi fi aidunnu ẹ han lori bi wọn ṣe pa Deborah Samuel nipakupa


Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti fi aidunnu ẹ han lori bawọn kan ṣe da ẹmi Deborah Samuel, to jẹ akẹkọọ nileewe olukọni  Sheu Shagari, ni Sokoto legbodo lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o sọrọ odi si Anọbi .

Ọkunrin naa sọ pe o jẹ ohun ẹdun ọkan pe iru nnakn bẹẹ si le maa waye nilẹ Hausa nibi ti aye laju de yii. O ni o jẹ ijakulẹ fawọn agba ilẹ Hausa pe wọn ko le pese aṣiwaju rere fọjọ iwaju awọn eeyan wọn.

Ninu atẹjade to fi sita fawọn oniroyin lo ti sọ pe bi wọn ṣe da ẹmi Deborah, to jẹ akẹkọọ ni ẹka ti wọn ti n kọ nipa ounjẹ iyẹn ‘Home Economic’ legbodo, l’Ọjọbọ, Tọsidee, jẹ aburu nla, to si yẹ ki wọn tete gbe igbesẹ le lori.

O ni ‘’ Latigba ti mo ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun, mi o le sun rara, ti mo si n ro nipa bi iru iṣẹlẹ aburu ọhun ṣe le waye lorileede yii tawọn kan ti imọ wọn ko kun to ninu Islam, pa Deborah danu, iru ẹmi buruku wo la le sọ pe o gbe iru awọn eeyan bẹẹ wọ’’

‘’ Ibeere ti mo tun wa n beere lọwọ ara mi ni pe ki lo de ti iru nnkan bẹẹ ko ṣe waye ni Aarin gbungbun orileede yii, Iyẹn ni pe nnkan tawọn aṣekupani ọhun sọ ni pe awọn eeyan ko gbọdọ ni igboya lati sọrọ lori nnkan to ba nigbagbọ ninu ẹ.’’

Oluponlongo Atiku Abubakar, fun ipo aarẹ, lọdun 2019, tun tẹ siwaju pe bawo ni a ṣe fẹẹ tẹsiwaju lati le jẹ ki idajọ ododo waye, bakan naa, la tun ṣe fẹẹ gbara wa lọwọ awọn iran to le wu, ti wọn ṣe aburu lọjọ iwaju.

Ọtunba tun fikun ọrọ ẹ pe’’ Oju ti mo fi n wo ọrọ yii ni pe ikuna lo jẹ fawọn aṣiwaju ilẹ Hausa, o ni nibo lo wa ninu Kuran, to ti sọ pe gbogbo Tom, Dick tabi Harry,tabi gbogbo Ahmed, Osama tabi Abdul gbọdọ mu ẹsin Islam ni dandan,. O waa beere pe ta ni yoo ilẹ Hausa lọwọ ara wọn, tabi gba Naijiria lọwọ Hausa.

O wa lo akoko ọhun lati sọ fawọn araalu pe bi eto idibo yii ṣe n sunmọ etile lati lo igboya lati yan aṣaaju rere ti yoo gba wọn lọwọ ipenija ta a n koju lọwọ bayii.

 


No comments:

Post a Comment

Pages