Obìnrin mílíọ̀nù márùn-ún ni yóò dìbò fún Aṣíwájú ní Èkó nìkan- Awọn Obinrin SWAGA'23 Eko - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 13 May 2022

Obìnrin mílíọ̀nù márùn-ún ni yóò dìbò fún Aṣíwájú ní Èkó nìkan- Awọn Obinrin SWAGA'23 Eko


 

Ẹgbẹ to nii ṣe fun erongba ilẹ Yoruba, tawọn obinrin, iyẹn SWAGA’23, ti ṣeleri pe awọn yoo ri pe miliọnu marun-un ibo wọn ni yoo ti ipinlẹ Eko, wa fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, fun ibo aarẹ to n bọ.

 

Wọn sọrọ yii lakooko ti wọn ṣefilọlẹ SWAGA tawọn obinrin, eyi to waye ni Haven Event Centre, ni Ikẹja G.R.A, nibi ti agba olorin fuji nni Abbas Akande Obesere, ti fere da wọn lara ya.

 

Nibi eto ọhun ni Ọnarebu Mọnsuru Alao, ẹni ti Ọnarebu Ọlọruntọba Oke ṣoju fun, nigba to n  ki awọn eeyan kaabọ, lo  fi idunnu ẹ han lori bawọn obinrin ṣe tu yaya jade lọjọ naa lati wa ṣatilẹyin fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu.

 

Ninu idanilẹkọọ  to ṣe lọjọ naa, ti akọle ẹ n jẹ ‘Ipa obinrin nidii oṣelu, iṣọkan ati alaafia’’ Ọnarebu Ayọ Omidiran, to jẹ alakoso fawọn obinrin lapapọ fẹgbẹ SWAGA, o ṣakiyesi pe ipa pataki lawọn obinrin n ko gẹgẹ bi iya, ati pe lara iṣẹ wọn ni lati ko awọn eeyan jọ fun nnkan rere.

 

Nigba to n ki awọn aṣoju lati ipinlẹ Ọṣun, Ọyọ, Ogun, Ondo ati Eko kaabọ sibi ayẹyẹ ọhun Ọnarebu Bọlanle Akinyẹmi-Obe to jẹ alaga ijọba ibilẹ Coker-Aguda LCDA, tẹlẹ, to tun wa jẹ alaga SWAGA fawọn obinrin nipinlẹ Eko, ni bawọn ṣe ṣeto ayẹwo oju lọfẹẹ jẹ ọna lati jẹ ki wọn mọ pataki oju lagọọ ara ati lati jẹ kiwọn mọ pe ilera loogun ọrọ.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ninu ọrọ ẹ, eyi ti Arabinrin Cecilia Bolaji Dada, to jẹ kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin jẹ lorukọ ẹ lo ti dupẹ lọwọ SWAGA’23, lori awọn ipa ti wọn ti ko lori atilẹyin erongba wọn fun Aṣiwaju, ati eyi ti wọn ṣe fun ijọba oun .

 

Nibi ayẹyẹ ọhun ni wọn ti fami ẹyẹ da Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu, atawọn iyawo Gomina bii Dokita Ibijọke Sanwo-Olu, Kafayat Oyetọla, Florence Ajimọbi ,Betty Akeredolu.

 

 Awọn yooku ni Ọtunba Titi Pọnnle. Folukẹ Etteh, Adejọkẹ Adefulire, Sarah  Sosan, Ranti Adebule,. Olurẹmi Hamzat ai Oloye Iyaafin Kẹmi Nelson.

 Lẹyin ẹ ni Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye , to jẹ alaga ẹgbẹ naa lapapọ ṣefilọlẹ awọn igbimọ obinrin naa nibi ti Ọnarebu Akinyẹmi-Obe jẹ alaga wọn, nigba ti Fatima Bello, jẹ alakoso ti Nikky Orisarayi, jẹ akọwe tuntun fẹgbẹ SWAGA, ipinlẹ Eko.

 

Lara awọn to tun wa nibẹ lọjọ naa ni Ọnarebu Oye Ojo, Ọnarebu Bọsun Ọladele, akọwe ẹgbẹ,  Alagba Ọlọruntọba Oke, akapo, Ọnarebu Deji Jakande, pẹlu Ọnarebu Akeem Muniru atawọn eeyan mii in.

 


No comments:

Post a Comment

Pages