Ko saaye fun daku-daji aarẹ lorileede yii mọ- Ṣaraki - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 9 May 2022

Ko saaye fun daku-daji aarẹ lorileede yii mọ- Ṣaraki


Aarẹ nile igbimọ aṣofin tẹlẹ, Dokita Bukọla Ṣaraki ti sọ pe, bi orileede yii ba fẹẹ ko ogo jari, wọn gbọdọ ni aarẹ ti yoo ni igboya lati koju awọn iṣoro to n koju eto aabo ati ọrọ aje. To si gbọdọ da pe daadaa.

 

Ilu Abẹokuta ni ọkunrin yii ti sọrọ naa lakooko to n ba awọn aṣoju ọmọ ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP), tipinlẹ Ogun sọrọ, lori erongba ẹ lati jade dupo fun aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu naa.

 

Bukọla Ṣaraki, ẹni to ti kọkọ ya lọdọ Aarẹ tẹlẹ lorileede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, nibi to ti ba a ṣe ipade bonkẹlẹ,tun sọ aarẹ to ba le maa sare lọ soke, lọ sodo, to ni okun daadaa nikan lo le wa ọna abayọ si ijakulẹ eto aabo, ọrọ aje to dẹnukọlẹ  ati aini isọkan lorileede yii.

 

O tun ṣalaye pe a n fẹẹ aarẹ ti yoo ni igboya daadaa, ti yoo le duro lori ọrọ ẹ, o ni fun apẹẹrẹ fọdun mẹrin toun fi jẹ olori ile igbimọ aṣofin agba, oun duro ti orileede yii nitori oun ni nnkan toun nigbagbọ ninu ẹ.

 

O rọ awọn aṣoju ki wọn jẹ ki wọn wa ẹni to ni agbara, to da pe, ti kii ṣe foniku, fọla dide, nitori akoko ta a wa lakooko yii, ẹni ti ilera ẹ pe nikan lo sọ pe o le ṣe.

 

Bukọla Ṣaraki, ti Abubakar Kawu Baraje, ẹni to jẹ alaga tẹlẹ fẹgbẹ oṣelu PDP lapapọ kọwọrin pẹlu ẹ tun sọ pe a ko fẹẹ aarẹ to jẹ pe yoo paṣẹ ko nii le yẹ aṣẹ naa wo.

 

O ni pẹlu eyi toun ka silẹ ọhun, oun nigbagbọ pe oun lagbara, toun si da pe lati le ṣe, O nigbagbọ oun ni pebi aarẹ ba le ni agbọye pẹlu awọn to n ṣofin, yoo tun jẹ iranlọwọ fun un lati bori ipenija lori eto aabo ati ọrọ aje lorileede yii.

 

Amọ nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, lẹyin to pari ipade bonkẹlẹ to ṣe pẹlu Oloye Ọbasanjọ, o sọ pe akoko ti orileede yii wa, wọn niẹni ti yoo mu wọn bọ ninu ajaga ti wọn wa, ki i tun ṣe ẹni ti yoo tun dakun un.

 


No comments:

Post a Comment

Pages