Ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni W2W4DA, ti wọn ṣatilẹyin fun Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, to n dije fun ipo aṣoju nile igbimọ aṣofin fun ẹkun Ogun West, ti sọ pe gbogbo awọn oloṣelu ti wọn ko ra wọn jọ pọ sibi kan, ti wọn n wa ọna lati ma jẹ ki oludije wọn yii gba tikẹẹti labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ni wọn yoo jabọ lojiji.
Ninu atẹjade ti Ọmọọba Fẹmi Dokunmu, to jẹ agbẹnusọ fẹgbẹ ọhun fi sita, eyi ti Dokita Kunle Salakọ, to jẹ alaga ẹgbẹ yii fọwọ si ni wọn ti sọ pe awọn oloṣelu kan ninu ẹgbẹ APC, ti n lọ kaakiri lati kọwọ bọwe adehun ti wọn fi tako Sẹnetọ lati ma ṣe jẹ ko ṣoju Ogun West, ninu ibo to n bọ naa.
Gẹgẹ bi ẹgbẹ ọhun ṣe wi, wọn lawọn iwadii tawọn ṣe jẹ ko di mọ pe ẹni to ti fi gba kan jẹ oludije gomina lati Ogun West, ti wọn lo nigbagbọ pe ogun oun ni lati maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn agba oṣelu nilẹ Yewa, ti ko le jawe olubori ni wọọdu ẹ, ni wọn sọ pe oun lo ṣaaju iditẹ tuntun ọhun.
Ẹgbẹ ọhun tun sọ pe gbogbo ipinnu ẹ yii ko tun irun kankan lara awọn, ṣugbọn awọn fẹẹ jẹ ji gbogbo araalu mọ awọn igbesẹ laburu yii nipa lilo awọn ayederu orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ ti ko si lati le jẹ ki ẹhonu ti wọn n gbe kaakiri naa ni atẹwọgba.
W2W4DA wa lo anfaani naa lati sọ fawọn eeyan pe oludije naa iyẹn Sẹnatọ Solomon Ọlamilekan Adeọla, koju oṣuwọn lati ṣoju Ogun West, gẹgẹ bi ofin orileede yii ṣe sọ paapaa julọ ninu ofin APC.
Wọn wa gba gbogbo awọn agba oloṣelu ti wọn lawọn ọbayejẹ naa fẹẹ lo lati da nnkan ru lati lo igboya lati sunmọ Yayi, ki wọn le mọ ootọ, ki ootọ naa si sọ wọn di ominira.
Wọn wa pari ọrọ wọn wọ pe gbogbo ọna lawọn yoo gba lati tẹsiwaju lati ko awọn eeyan jọ kawọn eeyan Ogun West fi mọ pe Yayi nikan ṣoṣo ni Ọlọrun yan, to si ṣe logo fun ipo sẹnetọ Ogun West fọdun 2023.
No comments:
Post a Comment