Satide ọsẹ yii ni wọn yoo jawe oye Arẹmọ Ọba ilẹ Yewa le Yayi lori ni Ilaro - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 8 May 2022

Satide ọsẹ yii ni wọn yoo jawe oye Arẹmọ Ọba ilẹ Yewa le Yayi lori ni Ilaro


 

Gbogbo eto lo ti bayii fun ayẹyẹ ifinijoye Arẹmọ Ọba ilẹ Yewa, ti wọn yoo  fi Sẹnetọ Adeọla Ọlamilekan, tọpọ mọ si  Yayi, to jẹ aṣofin nile igbimọ aṣofin, niluu Abuja,  jẹ lọjọ Abamẹta ọsẹ yii, niluu Ilaro.

 

Gẹgẹ bi atẹjade ti Oloye Kayọde Ọdunaro, to jẹ oludamọran pataki fun ọkunrin naa lori eto iroyin fi sita lonii, lo ti sọ pe wọn yoo tun lo ayẹyẹ ọjọ naa lati fi sami ọdun mẹwaa, ti  Olu-Ilẹ Yewa, Ọba Kẹhinde Olugbenle, gori itẹ awọn baba ẹ, ti wọn yoo tun fi ṣefilọlẹ iwe itan ọba naa pẹlu,ti Alhaji Aliko Dangote, Ahmed Lawan, to jẹ aarẹ nile igbimọ aṣofin niluu Abuja ati Oloye Kessington Adebutu, yoo bawọn ṣefilọlẹ ẹ naa. 

 

 

 A o ranti pe lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021, ni awọn igbimọ lọbalọba nilẹ Yewa, kọ lẹta si Yayi pe awọn fọwọ si Arẹmọ Yewa lati nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin, nitori awọn ilakaka ẹ to ti ṣe lati mu idagbasoke ba ilẹ Yewa lapapọ.

 

Loju ẹsẹ ti wọn ni aṣofin ọhun ti gba lẹta naa ti Ọba Olugbenle, gẹgẹ bi Olu Yewa, fọwọ si loun naa ti gba apọnle ati iyi ti wọn fun naa.

 

Lara awọn ti wọn n reti lọjọ naa ni Aarẹ ile igbimọ aṣofinAhmad Lawan, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ,to jẹ Gomina ipinlẹ Ogun, Arẹmọ Oluṣẹgun Ọṣọba, Ọtunba Gbenga Daniel,Ọgbẹni Boss Mustapha,akọwe ijọba apapọ, Ọọni Ile- Ifẹ, Ọba Adeyeye Ogunwusi atawọn eeyan jakanjakan ni wọn n reti lọjọ naa.

 

Bakan naa la gbọ pe wọn yoo tun fi iyawo Yayi, Temitọpẹ jẹ Yeye Arẹmọ,Ọtunba Akeem Ade Adigun(Sokopao) yoo joye  Apagunpọtẹ ilẹ Yewa, Alaaji Ibrahim Dende Egungbohun naa yoo jawe oye Oluọmọ ati Salmot Badaru, igbakeji Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun naa yoo joye Bẹẹrẹ ilẹ Yewa.

 

 Sa


No comments:

Post a Comment

Pages