Gbogbo Ọdunaro ti ranṣẹ ikini ku oriire si Kayọde Ọdunaro, ẹni to jẹ oludamọran pataki fun eto iroyin fun Sẹnetọ Solomon Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, lori bi wọn ṣe jawe oye tuntun lee lori gẹgẹ bi Majẹobajẹ ilu Ilaro, Yewa.
Eyi ti Ọba Kẹhinde Olugbenle, Olu tiluu Ilaro, jawe oye ọhun lee lori. Ninu atẹjade to Dokita Ọlatunji Ọdunaro fọwọ si lorukọ idile ọhun ni wọn ti fi idunnu wọn han ọi oloye tuntun naa.
Atẹjade ọhun lo ka bayii’’ Pẹlu inu dundun, ayọ la fi gba iroyin naa wọle, ta a si tun fi adura ran ọ lọwọ pe Ọlọrun Ọba yoo tubọ fun ọ ni ẹmi gungun ati alaafia ti waa fi lo oye naa pẹ’’.
‘’A ki Majẹobajẹ ilẹ Yewa ku oriire oye tuntun yii. Ọjọ ayọ lo jẹ fun wa pe a n ba eeyan wa to ti kopa tojọju kaakiri lati fi gbe ogo idile wa ga. Ki i ṣe ọrọ ẹnu lasan, oye yii tọ si ọ, nitori awọn iṣẹ ẹ fun idagbasoke ilu Ilao lakooko to fi jẹ alaga igbimọ ayẹyẹ ayajọ Oronna.’’
‘’ Adura wa ni pe ki Ọlọrun maa daboobo bo ẹ, ko si tun maa tọ ẹ sọna ninu gbogbo irinajo ẹ, ninu aye yii, lẹẹkan si, a ki ọ ku oriire..
No comments:
Post a Comment