Wọn ni o ṣe e ṣe ki Ọnarebu Tunji Akinosi gba tikẹẹti aṣoju-ṣofin agbegbe Ado-Odo/Ọta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 24 May 2022

Wọn ni o ṣe e ṣe ki Ọnarebu Tunji Akinosi gba tikẹẹti aṣoju-ṣofin agbegbe Ado-Odo/Ọta


Bi iroyin to n lọọ nigboro yii ba fi le jẹ ootọ, o ṣeeṣe ko jẹ pe Ọnarebu Tunji Akinosi, to jẹ kọmiṣanna fọrọ igbo iyẹn fọrẹsiri nipinlẹ Ogun, ni wọn yoo fun ni tikẹẹti oludije fun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, fun ipo aṣoju-ṣofin fun ẹkun Ado-Odo/Ọta niluu Abuja fọdun 2023.

Gẹgẹ bi a ṣe pọ lati ẹnu awọn to sunmọ Gomina Dapọ Abiọdun, pe ipade abẹlẹ kan ti waye laarin Gomina naa atawọn agba aṣaaju ẹgbẹ naa ni ẹkun Ado-Odo/Ọta, nibi ti wọn lo ti sọ fawọn pe oun fẹẹ ẹni to le ṣiṣẹ pẹlu oun, ti yoo le mu erongba iṣejọba ṣẹ fun ipo ẹlẹẹkeji toun mura silẹ yii.

Ohun ta a si n gbọ ni pe Tunji Akinosi, lawọn aṣaaju agbegbe ọhun foju sun gẹgẹ bi ẹni to le ṣiṣẹ naa ti wọn ba fun-un ni oore ọfẹ lati lọ ṣoju wọn nibẹ.

Bẹẹ ni wọn tun sọ pe ẹni to ti wa nipo naa lọwọ bayii, iyẹn Ọnarebu Jimoh Ojugbele, ni wọn lo jẹ pe oye aye ọjọun lo si wa lori ẹ, eyi ti ko le mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba agbegbe naa bi wọn ba tun le fun ni tikẹẹti yii.

Ẹni to ba wa sọrọ naa sọ pe “ Idi niyii ti Gomina fi sọ fawa aṣoju  nipinlẹ Ogun pe oun yoo ṣatilẹyin fun ẹni to ba le ṣiṣẹ pẹlu ẹ ti nnkan yoo fi tubọ pada bọ sipo’’

“Gomina tun sọ fun wa pe oun ṣetan lati ṣagbara oun nipinlẹ yii ṣugbọn oun fẹẹ awọn to fẹẹ dije fun ipo yala ile igbimọ aṣofin tabi ṣoju-ṣofin, ti wọn yoo nigbagbọ ninu igbekalẹ ati ilakaka oun ki ipinlẹ yii fi le tẹsiwaju.

Idi niyii ti Ọgbẹni Ọlawale Iyanda, ọkan lara agba lagbegbe ọhun fi sọ pe ko si pe awọn siyemeji,Ọnarebu Akinosi, lawọn agbaatawọn ọmọ ẹgbẹ mu, ti wọn si ti ṣeleri lati ṣiṣẹ pẹlu ẹ lakooko ibo abẹle ti yoo waye laipẹ yii.

O ni wọn ti sọ fawọn pe ọkunrin yii yoo tubọ mu idagbasoke ba Ado-Odo/Ota, gẹgẹ bi aṣofin atawọn iriri ro ti ni nidii oṣelu. Lara  awọn eto ti wọn sọ pe ọkunrin naa ni idagbasokelawọn igberiko, igbelarugbẹ eto ọgbin, irolagbara awọn ọdọ atawọn obinrin to fi mọ reran awọn arugbo atawọn to ku diẹ kaato lọwọ.  

Bẹẹ naa ni wọn sọ pe o ni lọkan awọn iṣẹ akanṣe, idasilẹ ileeṣẹ nla, igbelarugẹ eto ẹkọ, aabo ati ilanilọyẹ ni gbogbo igba. Wọn ni Ọnarebu Tunji Akinosi, ti ṣetan lati gba iṣẹ ọhun bi wọn ba fun un laaye, nitori o ti wa ni imurasilẹ ẹ lati bi ọdun meloo kan sẹyin.

“Ni bayii, ko si aye ere mọ, ỌnarebuTunji Akinosi, tawọn eeyan mu, ti ṣeleri gbogbo nnkan nnkan toun ni lọkan loun yoo muṣẹ’’ Oludele ọkan lara awọn agba oṣelu lo sọ bẹẹ.

 


No comments:

Post a Comment

Pages