Bo tilẹ jẹ pe ko tii pẹ ti Ọmọọba Babajide Fadairo,fi erongba ẹ han lati dije dupo fun aṣoju-ṣofin, fun ẹkun Ifọ/Ewekoro, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, niluu Abuja, eyi to waye ni ọfiisi ẹgbẹ ọhun to wa ni Itori.
Oludije ọhun to tun jẹ ọkọ fun Ọmọọba-binrin Fọlaṣade Ogunwusi Fadairo, ẹgbọn Ọọni Ile-Ifẹ, fi idunnu ẹ han saawọn aṣaaju ẹgbẹ naa fun atilẹyin ti wọn n ṣe fun Gomina Dapọ Abiọdun, lori iṣakoṣo ẹ nipinlẹ Ogun.
Bakan naa lo tun wa rọ latto tẹsiwaju nipa atilẹyin wọn ki wọn si rii pe Gomina ọhun gba tikẹẹti lati dije lẹẹkeji, ninu ibo to n bọ lọdun 2023.
Ọkunrin ọhun tun sọ pe ayipada rere ni yoo deba awọn eto ilera lagbegbe ọhun bẹẹ lo tun ṣeleri ironilagbara fawọn olugbe paapaa julọ awọn ara ọja lọkunrin ati lobinrin, eyi ti yoo fun wọn ni oore ọfẹ ẹyawo fun wọn.
Bẹẹ lo tun sọ pe iranlọwọ owo yoo tun wa lati fi ran awọn ọmọleewe girama oni ipele kẹta girama kekere ati onipele kẹta fawọn agba girama pẹlu.
Bẹẹ ni Ọmọọba Jide Fadairo, tun fikun ninu ọrọ ẹ pe oun gbero awọn ẹrọ igbalode fun anfaani awọn eeyan agbegbe ọhun, o waa rọ wọn lati jumọ sọkan fi ibo wọn gbe oun wọle ninu ibo abẹle to yoo kọkọ waye lati le gba tikẹẹti lorukọ ẹgbẹ naa.
Ọkunrin yii tun ṣeleri idagbasoke ati imayedẹrun lati ọwọ ijọba apapọ si agbegbe Ifọ/Ewekoro. O waa pari ọrọ ẹ pe oun yoo ri pe oun ṣiṣẹ pọ pẹlu Gomina Dapọ Abiọdun, ki idagbasoke atawọn ohun rere le tẹ wọn lọwọ ni agbegbe toun fẹẹ ṣoju-ṣofin le lori. Bakan naa lo ni awọn ọdọ naa yoo jẹ anfaani ipese iṣẹ lakooko toun.
No comments:
Post a Comment