Mariam Gbadamọsi
Beeyan ba de gbọngan DLK, to wa ni Leme, lọjọ Tusidee, ana, ti o ri bi ero ṣe pọ to bi omi, yoo ti mọ ohun itan nla kan lo fẹẹ ṣẹlẹ, bẹẹ si, oun itan gba a ni, nitori lọjọ naa ni Ọnarebu Adekunle Akinlade pe awọn eeyan paapaa awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), jọ to kede ipinnu ẹ lati di gomina ninu ibo to n bọ lọdun 2023.
Ara ọtọ lọjọ naa tun jẹ nitori ṣe lawọn ti wọn tun jọ fẹẹ dije fun ipo yii ni abẹ ẹgbẹ oṣelu kan naa tun wa yẹ ẹ si. Awọn naa ni Amofin Biyi Ọtẹgbẹyẹ ati Arabinrin Mọdelele Ṣarafa- Yusuf, tawọn naa si sọrọ imoriya lati fi han pe ifẹ wa laaarin wọn.
Bẹẹ lo tun ṣe jẹ pe Oloye Derin Adebiyi, ṣaaju awọn oloye ẹgbẹ naa labẹ Sẹnetọ Ibikunle Amosun wa sibẹ lọja naa. Bakan naa ni ẹsẹ o gbero fawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti wọn wa lati ṣatilẹyin fun ọkunrin ti wọn n pe mi Tripple A yii.
Ninu ọrọ ti Akinlade, to jẹ oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Allied People's Movement (APM), nipinlẹ Ogun, lọdun 2019, sọ lakooko to n fi erongba ẹ han lo ti sọ pe ijọba oun yoo mu eto aabo awọn araalu ni Pataki, tawọn eeyan yoo si maa gbe igbe alaafia.
Ọkunrin naa sọ pe idagbasoke ko le ba awujọ tawọn bii adaluru, apaniyan, ajinigbe atawọn iwa ọdaran mii-ii ba ti wa. O ni bi wọn ba le fun oun ni tikẹẹti labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, lati dije fun ipo gomina iṣakoṣo oun yoo ṣeto awọn alaabo ti wọn yoo fopin sawọn ọdaran yii lawujọ.
Bakan naa lo tun mẹnuba awọn eto to ni fun eto ọgbin,eto ẹkọ, pipa owo wle ilera atawọn nnkan mii in ninu ijọba ẹ,eyi to ṣeleri pe owo to to biliọnu mẹwaa naira ni yoo maa wọle fun ipinlẹ yii ni oṣooṣu.
O waa dupẹ lọwọ gbogbo awọn to nigbagbọ ninu erongba pe ipilnlẹ Ogun n fẹẹ olugbala ti yoo mu ayipada rere wa, o ni olugbala ọhunsi ti de bayii. Bẹẹ lo tun sọ fawọn aṣoju ti wọn yoo dibo pe ki wọn foun laaye lati gba tikẹẹti, ki awọn ala rere yii le di amuṣẹ.
Akinlade tun sọ pe idunnu oun ni yoo jẹ bi wọn ba le pawọpọ fun oun ni anfaani lati le di gomina alagbada kẹfa, nigba ti yoo ba fi di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023.
O ni “ Bi a ṣe n gbaradi funibo abẹle l’Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ yii, mo rọ gbgbo ẹyin aṣoju igun yoowu ti ẹ le wa lati finu findọ dibo fẹni ti ẹ ba mọ pe yoo mu ilọsiwaju ba ipinlẹ Ogun fọdun mẹrin to n bọ’’
No comments:
Post a Comment