Ṣowunmi fẹẹ ki wọn tu awọn oloye ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ogun ka - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 20 May 2022

Ṣowunmi fẹẹ ki wọn tu awọn oloye ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ogun ka


Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti rọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun, to wa niluu Ibadan lati fagile idajọ ile-ẹjọ giga ti Ogun, nibi to ti bẹbẹ pe ki wọn tu awọn oloye ẹgbẹ naa ka


Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, oludije gomina yii lo gba ile-ẹjọ giga ni Ogun, nibi to ti tako ọrọ ti oludije akẹgbẹ ẹ, Ọnarebu Ladi Adebutu, pe lara awọn oloye ẹgbẹ naa lo ra fọọmu toun fẹẹ fi dije foun.

Ọkunrin yii ni oun fẹẹ ki wọn tu awọn oloye ẹgbẹ ọhun ka, nitori ko si igbagbọ ninu wọn ati pe ki wọn tun da wọn lẹkun lati ma ṣe sakoso ibogbogboo tijọba ibilẹ ati tipinlẹ.

Ṣugbọn ṣe ni Adajọ A A Akinyẹmi, to n gbọ ẹjọ naa da awọn ẹbẹ naa nu, nibi idajọ kan to gbe kalẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii,  idi niyii ti Ṣowunmi tun ṣe pe ẹjọ kotẹmilọrun, lati fi le gbọ ẹjọ ọhun daadaa.

Bakan naa la gbọ pe ọkunrin yii tun ti kọ lẹta sawọn oloye ẹgbẹ wọn lapapọ lori ki wọn tu awọn oloye yii ka naa ni.O sọ pe bi awọn oloye ẹgbẹ yii ba fi le sakoso ibo abẹle ẹgbẹ naa, o ṣeeṣe ki wọn maa ni oludije fun ipo gomina ninu ibo to n bọ yii.


No comments:

Post a Comment

Pages