Alailẹkọọ lawọn oloṣelu to ba tabuku ori ade ni Yewa- Popoola - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 21 May 2022

Alailẹkọọ lawọn oloṣelu to ba tabuku ori ade ni Yewa- Popoola



Igbimọ agba fẹgbẹ oṣelu APC, ti Ogun West, ti sọ pe  alailẹkọọ lawọn oloṣelu ti wọn sọrọ odi sawọn ọba alaye, nitori ki i ṣe nnkan to tọna nilẹ Yoruba.

Alagba Bisiriyu Popoọla, lo rọ yii lakooko to dahun si ibeere lori bawọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu naa ṣe fojoojumọ foko ọrọ ranṣẹ si awọn ọba alaye nitori Aṣofin Solomon Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, nitori ipo aṣofin tọkunrin naa fẹẹ dije fun lati Ogun West.

O ni lọjọ ti alaye ti daye igbakeji ọọsa, ni wọn ka awọn ọba alaye si nilẹ Yoruba, ẹni to ba si yaju si wọn, awọn alaalẹ ni wọn yaju si.  Nigba to n sọrọ ni tiẹ, Oloye Mufutau Ajibọla, to jẹ alaga igbimọ fẹgbẹ oṣelu APC, ni Ogun West, sọ pe awọn tako ọrọ tawọn kan ti wọn pe ara wọn ni ``Committe of Ogun Concerned Ogun West Patriot'' gbe jade nibi ti wọn ti fi ilodi wọn han si Aṣofin Ọlamilekan Adeọla, to n jade dupo fun sẹnetọ lọdun 2023, nibi ti wọn ti sọ pe ajoji ni ọkunrin naa ki i ṣe ara wọn.

Oloye Ajibọla sọ pe irọ to jinna sootọ, nitori pe gbogbo ẹnu loun fi le sọ pe ojulowo ọmọ Yewa, ni Yayi, o si ni ẹtọ labẹ ofin lati dije fun ipo to ba wuu nilẹ Yewa.

Alaga naa tun fi kun ninu ọrọ ẹ pe ko si lara awọn obinrin meji ti wọn wa ninu awọn ti wọn sọrọ naa, iyẹn Aṣofin Iyabọ Aniṣulowo ati Oloye Mary Ogunjọbi, ti ẹnu wọn gbaa lati sọ pe ẹnikan ki i ṣe ọmọ Yewa.

Bakan naa lo tun ṣalaye pe gbogbo igbimọ agba nilẹ Yewa, ni wọn lọwọ si nnkan tawọn n ṣe yii, nitori awọn mọ pe akoko ti to fun Yewa lati pa ẹnu pọ fi imọ sọkan.

O tun ṣalaye pe ko si ootọ ninu ọrọ ti wọn tun sọ pe awọn igbimọ agba APC yii gbe lẹyin ẹnikan fun ipo oṣelu yii, o ni gbogbo awọn oludije lawọn gba wọle, ẹni tawọn ọmọ ẹgbẹ ba si sọ ni. Ko si oludije kankan to ra awọn, nnkan to ṣe pataki fawọn ni pe kawọn ti ni aṣoju rere ti yoo mu ohun rere wọlu,tilẹ Yewa yoo si tubọ tẹsiwaju ninu idagbasoke.

O wa rọ gbogbo awọn ọmọ ilẹ Yewa lati ma ṣe jẹ kawọn kan tori ẹtanu oṣelu ba ohun rere to n bọ niluu jẹ, nitori awọn nigbagbọ pe bi Yayi, ṣe ṣe daadaa nipinlẹ Eko, yoo tubọ ṣe ju bẹẹ lọ to ba wọle ninu ibo to n bọ lọdun 2023.

Capt;


No comments:

Post a Comment

Pages