Ìdí tí iléeṣẹ́ Pelican ṣe fún Ajírébi lẹ̀bùn mọ́tó àti ilẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 21 May 2022

Ìdí tí iléeṣẹ́ Pelican ṣe fún Ajírébi lẹ̀bùn mọ́tó àti ilẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́ Victoria Akinpẹlu

 

Idunnu ṣubu layọ gbajumọ oṣere onitiata nni, Alagba Kayọde Ọlasẹhinde, ti gbogbo eeyan mọ si Ajirebi, lọsẹ to kọja, nigba ti Dokita Babatunde Adeyẹmọ, ọga agba ileeṣẹ Pelican Estate, fun ọkunrin naa ni ẹbun mọto olowo nla,ti iye ẹ to miliọnu mẹrin abọ naira bẹẹ lo tun fun ni ilẹ pẹlu.

 

Lọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni ayẹyẹ ọhun waye niluu Abẹokuta, lakooko to n ṣami ayẹyẹ ọjọọbi, ọdun kẹtalelogoji. Ajirebi to jẹ aṣoju ileeṣẹ naa ni wọn fun lẹbun nla ọhun lati fi ẹmi imoore ati ipa to ti ko fun ilọsiwaju ileeṣẹ ọhun.

 

Lakooko ti wọn ṣe ayẹyẹ iwẹjẹ wẹmu fun ti ọjọọbi ọhun ni ọga ileeṣẹ ọhun ti kede ẹbun nla yii, eyi to si jẹ iyalẹnu fun ọpọ awọn eeyan ti wọn wa nibẹ lọjọ naa.

 

Nigba to n sọrọ lọjọ naa, Dokita Babatunde Adeyẹmọ, ṣapejuwe Ajirebi, gẹgẹ bi ẹni to niwa irẹlẹ,  ti irawọ awọn mejeeji si bara mu lati jọ siṣẹ papọ. To si jẹ ẹni ti ki woju owo ko to ba eeyan ṣiṣẹ pọ.

 

O sọ pe oun awọn ilẹ Pelican jẹ eyi to sọwọn laarin awọn iyooku ẹ. O ni ki i ṣe nitori owo lo n ṣe n ṣe òwò naa. O ni Ọlọrun sọ awọn di okuta ti ọmọle kọ ti to wa di igun ile.

 

Ninu ọrọ Ajirebi, o dupẹ lọwọ ọga ileeṣẹ Pelican, fun oore nla manigbagbe to ṣe foun yii, o ni iru ọkunrin naa sọwọn lawujọ. Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni Iyawo Ajirebi,  atawọn ọmọ ẹ meji.


No comments:

Post a Comment

Pages