Aarẹ orileede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti sọ pe pẹlu ipo ti Naijiria wa bayii, nnkan ta a n fẹ ni aṣaaju to ni ọgbọn, imọ ati erongba rere lati fi tukọ.
O sọrọ yii lakooko to n gbaMohammed Hayatu-Deen, oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, ninu ibo to n bọ lalejo niluu Abẹokuta. O sọ pe oun ni erongba ara ọtọ fun orileede yii niwọngba to jẹ pe ko sibomii-in toun le lọ.
O ni bi aṣaaju rere ba wa, gbogbo ipenija ta a n koju lori ọrọ aabo, ko yẹ ko gba wa ju ọdun meji lọ ti gbogbo ẹ yoo fi ni yanju. O ni ko si orileede kankan toun le lọ idi niyii toun ṣe pinnu lati duro sibẹ.
Ọbasanjọ tun sọ pe “ Awọn kan maa n sọrọ kan pe ero inu awọn eeyan kuru, to ba ri bẹ, ọpọ aṣiṣe ta a ti ṣe ko yẹ ka ṣe , lootọ. A ni akọsilẹ tawọn eeyan le yẹ wo lati mọ nnkan ti wọn ba fẹ , amọ nnkan to wu ki wọn fẹ gbọ, mo nigbagbọ ninu eeyan bi tiẹ, gẹgẹ bo ṣe sọ pe akoko taa wa yii ko dabi tẹlẹ lorileede yii’’
O tun ṣalaye pe nnkan mẹrin lo wa si ọkan oun laarọ ọjọ naa, akọkọ ni imọ, ẹlẹẹkeji ni erongba, ikẹta ni ipinnu ati arojinlẹ. O ni ti mẹrẹẹrin yii ba fi le wa lorileede yii fun aṣaaju ti yoo tukọ, a jẹ pe iṣoro wa ti dinku niyẹn,
Ninu ọrọ ti Hayatu-Deen, lo ti kọkọ sọ pe awokọṣe rere ti Ọbasanjọ ti fi silẹ loun yoo lo lati fi ṣeto iṣejọba rere, oun si lawọn tun fi n ṣe ipolonglo.
Lẹyin to kuro nibẹ, lo lọ si oluuleṣẹ PDP, to wa ni Abẹokuta, nibi to ti bawọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ nipa erongba ẹ ti wọn ba le fun ni tikẹẹti lati dije fun ipo aarẹ orileede yii.
No comments:
Post a Comment