O n rugbo bọ; Awọn oludije gomina APC mẹrin yari mọ Dapọ Abiọdun lọwọ lori ibo abẹle - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 20 May 2022

O n rugbo bọ; Awọn oludije gomina APC mẹrin yari mọ Dapọ Abiọdun lọwọ lori ibo abẹle


Bi nnkan ṣe n lọọ yii, afaimọ ki gbogbo erongba Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun, lati gba tikẹẹti  dije lẹẹkeji ninu ẹgbẹ APC ni irọrun, ma ja si ofo, nitori bawọn oludije mẹrin yooku ti wọn jọ gba fọọmu, ṣe yari mọ ọn lọwọ, lori awọn etekete ti wọn lo fẹẹ lo nipa awọn aṣoju ti yoo dibo abẹle iyẹn pamari.

Awọn oludije gomina ọhun ti wọn fẹhonu wọn han lori igbesẹ naa ni Biyi Ọtẹgbẹyẹ, Ọladunni Ọpayẹmi, Mọdele Ṣarafa-Yusuf, ati Adekunle Akinlade.

Nibi ti ọrọ de bayii, awọn eeyan ọhun ti lọọ fẹjọ sun alaga ẹgbẹ naa lapapọ, iyẹnSẹneto Abdullahi Adamu, lati tete wa nnkan ṣe si, nitori gbogbo ọgbọn alukọrọmi to fẹẹ lo lawọn ti mọ, tawọn ko si nii gba fun.

Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Yẹmi Sanusi pe ọrọ ẹ ko yatọ si ẹni to fẹẹ maa gbabọde fawọn yooku, to si n fi apa kan da apa kan si, ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Wọn ni ṣe lawọn eeyan ọhun kuna lati fi orukọ awọn aṣoju ti wọn yoo kopa nibi ibo pamari ọhun sita. Bẹẹ la tiẹ gbọ pe gbogbo awọn to fẹẹ kopa nibi ibo abẹle ọhun ni Dapọ Abiọdun, ti mori wọn mọ abẹ.

Awọn oludije ọhun tun ṣalaye pe awọn ti wọn ṣe ti Gomina nikan ni wọn fẹẹ jẹ ko kopa. Ohun ti wọn lo si n dun awọn ni pe awọn aṣoju ti wọn jẹ tawọn oludije yooku ni wọn kọ jalẹ lati fun ni fọọmu.

Awọn eeyan ọhun wa rọ alaga ẹgbẹ naa lapapọ lati jẹ ki wọn ṣe ibo abẹle ọhun gẹgẹ ni gbangba lasa n ta, nibi tawọn olukopa yoo ti ni ominira lati dibo fẹni ti wọn ba n fẹ, laini si wahala tabi idunkoko.

Wọn wa rọ Adamu lati tete gbe igbesẹ ki ọrọ ọhun ma ba yiwọ.


No comments:

Post a Comment

Pages