Bi iroyin to tẹ wa lọwọ yii ba fi le jẹ oootọ, afaimọ kawọn ọmọ ileewe yunifasiti lorileede ma pẹ nile bi ti ọbọ, nitori bi wọn ṣe ni ẹgbẹ awọn olukọ iyẹn Academic Staff Union of Universities, (ASUU), tun ti fi oṣu meji kun iyanṣẹlodi onikilọ ti wọn gun le.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ipinnu ọhun waye nibi ipade tawọn oloye ẹgbẹ naa ṣe niluu Abuja.
Wọn ni bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii pariwo ẹ sita faraye gbọ, amọ iroyin ta a n gbọ ni pe wọn gbọdọ ṣafikun iyanṣẹlodi ikilọ wọn yii, Laipẹ yii ni wọn sọ pe wọn yoo gbe abajade ọhun sita.
No comments:
Post a Comment