Ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, ti sọ pe awọn afurasi mọkanla lọwọ awọn ti tẹ lori nnkan ti wọn mọ nipa Olu-Agodo, Ọba Ọdẹtọla Ayinde, nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun, ti wọn dana sun laipẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti Hauwa Idris Adamu, to jẹ agbẹnusọ awọn ọlọpaa, ti ẹkun keji, Onikan, nipinlẹ Eko, fọwọ si, o sọ pe awọn mu awọn mọkanla ọhun nitori iwe ẹsun tawọn gba nipa iku ọba alaye ọhun
Gẹgẹ bi iwe ẹsun ọhun ṣe wi, wọn ni lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun yii lawọn gba iwe ẹsun naa lati ọdọ Ọdẹtọla Okuribido, ni orukọ ẹbi Okuribido, niluu Agodo, nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun.
Pe lọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kin-in ni, ọdun yii, ni wọn pa Ọba Ọdẹtọla Ọlajide Ayinde, Olu tilu Agodo, lati ọwọ ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Gbeminiyi Ṣotade, ti inagijẹ ẹ n jẹ Okon atawọn eeyan ẹ kan.
Wọn sọ pe ọba ti wọn pa yii lọ sinu abule ẹ lori ọrọ ilẹ lati bawọn yanju ẹ, to jẹ ti ẹgbọn ẹ, ṣugbọn lojiji lawọn ọmọọta, ti wọn tio aadọta, ti Gbeminiyi Ṣotade, ṣaaju yawọ ibudo naa, ti wọn si kọju ija sii nigba ti wọn sa awọn mẹta yooku ti wọn jọ wọ ninu mọto naa ladaa.
Bakan naa ni wọn tun kọ sinu iwe ẹsun ọhun pe ṣe lawọn afurasi naa ti ọba alaye yii sinu mọto ẹ ti nọmba ẹ jẹAPP 55 GF, nigba ti ẹnikan ti wọn pe ni Agbara, waa mọto naa lọ sinu igbo, nibi ti wọn ti da pẹtiroolu sii, ti wọn sii dana sun- un.
Agbẹnusọ awọn ọlọpaa naa waa darukọ awọn mẹta tori ko yọ lọjọ naa, awọn naa ni Alfa Wahab, Arabinrin Deborah Onilere ati Arabinrin’ Lydia Ọdẹtọla
Ni bayii, a gbọ pe awọn afurasi mọkanla tọwọ tẹ ọhun ti n fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọpaa, nigba ti wọn beere pe ki lo de ti wọn fi huwa naa, ohun ti wọn sọ pe wọn sọ ni pe Ajagungbalẹ ni ọba alaye naa.
Iwadii tun fi ye wa pe awọn ọlọpaa si n sa ipa wọn lati ri i pe ọwọ tẹ awọn yooku, ti wọn jọ ṣiṣẹ ibi ọhun.
No comments:
Post a Comment