Ọwọ tẹ awọn ogbologboo afurasi adigunjale marun-un ni Ipẹru - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 14 March 2022

Ọwọ tẹ awọn ogbologboo afurasi adigunjale marun-un ni Ipẹru


 

Awọn ogbologboo afurasi adigunjale marun-un ti wọn da awọn eeyan lọna ni Ipẹru/Ṣagamu/Ode- Rẹmọ, lọwọ ọlọpaa ti tẹ, ti wọn si ti n ka boroboro lori awọn iṣẹ ibi ti wọn ti ṣe.

 

Gẹgẹ bi ileeṣẹ awọn ọlọpaa Ogun, ṣe fi sita, awọn tọwọ tẹ ọhun ni  Mọruf Abidogun, Usman Adeyẹmi, Fisayọ Aliu, Afees Adeṣina ati Dauda Lekan.

 

Lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii ni wọn sọ pe ọwọ palaba awọn eeyan yii ṣẹgi, nigba tawọn kan ta ọga ọlọpaa, DPO, agbegbe Ogere, Waheed Oni,  lolobo pe awọn afurasi naa n jawọn eeyan lole, ti wọn si gbegi dina,

 

Loju ẹsẹ la gbọ pe DPO naa ti ṣaaju awọn eeyan ẹ lọọ sibi iṣẹlẹ ọhun, wọn ni bi wọn ṣe de ọhun ni wọn ri mọto Toyota Korola kan, ti nọmba ẹ jẹ  GGE 733 FL, tawọn to wa ninu ẹ fẹẹ maa sa lọ, amọ tawọn ọlọpaa naa gba tẹle wọn, ti wọn si mu wọn.

 

Ninu awọn iwadii tawọn ọlọpaa si ṣe fihan pe awọn eeyan ọhun nibi kan ti wọn n lo ni Eko, amọ lara wọn maa n wa si Ipẹru lati ṣiṣẹ ibi wọn, nitori ọkan lara wọn gbe nibẹ.

 

Lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn ni Ibọn ibilẹ ati mọto Toyota korola. Ni bayii, CP Lanre Bankọle, to jẹ kọmiṣanna fawọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ti wa paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi naa wa si Eleweran, niluu Abẹokuta, ki wọn si bẹrẹ iwadii wọn ni akọtun.

 

No comments:

Post a Comment

Pages