Ọlaniyi Fadahunsi ni oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Action Alliiance nipinlẹ Ọṣun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 12 March 2022

Ọlaniyi Fadahunsi ni oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Action Alliiance nipinlẹ Ọṣun


Lọjọ Abamẹta, Satide, ni ẹgbẹ oṣelu Action Alliance. AA, tipinlẹ Ọṣun, dibo yan Ọgbẹni Ọlaniyi Fadahunsi, gẹgẹ ni oludije gomina fun ibo to n bọ lọdun 2023.

Nibi ibo abẹle ọhun to waye ni ọfiisi ẹgbẹ naa to wa niluu Oṣogbo, ni ọkunrin naa ti na alatako ni ana bami pẹlu ibo mẹtadinlọgọrin si mẹfa pere.

Nigba to n sọrọ lẹyin ti wọn kede ẹ pe o jawe olubori, Ọgbẹni Ọlaniyi Fadahunsi, dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ ọhun fun ifẹ ti wọn ni si lati le jẹ oludije wọn ninu ibo naa

O tun ṣalaye siwaju pe gẹgẹ bi iṣẹ ti wọn gbe siwaju oun lati dije fun ipo ọhun, o loun ṣetan lati ṣiṣẹ naa pẹlu idaniloju pe awọn yoo bori ninu ibo naa.

O waa lo akoko ọhun lati bẹbẹ fun atilẹyin gbogbo ọmọ ẹgbẹ yii lati jẹ ki wọn jọ ṣe papọ, kawọn si jọ ṣaseyọri pẹlu ileri pe oun ko nii jẹ afibi-su- oloore.

Ninu ọrọ Ọnarebu Adekunle Rufai Ọmọ Ajẹ, to jẹ alaga ẹgbẹ naa lapapọ. O ni inu oun dun bi ibo naa ṣe waye nirọwọ-rọsẹ, ti ko si wahala kankan.

O waa sọ fun ẹni ti wọn jọ dije ti wọn ko wọle pe ko si ẹni to bori bẹẹ ni ko sẹni to fidi rẹmi, gbogbo wọn yoo jọ ṣiṣẹ pọ ni. O waa sọ pe pẹlu idaniloju pe bi ajọ INEC, ko ba kede ẹgbẹ naa gẹgẹ bi olubori ibo to n bọ, ko sẹnikan ti wọn yoo kede.

Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa lawọn alaga ẹgbẹ AA jakejado orileede yii bẹẹ lawọn ajọ eleto ibo INEC naa wa nibẹ, ti wọn wa ṣamojuto.

 

No comments:

Post a Comment

Pages