Ọ̀gá àwọn kọsitọọmu fẹmi imoore han sawọn ọba alaye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 11 February 2022

Ọ̀gá àwọn kọsitọọmu fẹmi imoore han sawọn ọba alaye



Nnadi Dera, to jẹ ọga agba fun ẹṣọ aṣobode, iyẹn kọsitọọmu, nipinlẹ Ogun, ti fi ẹmi imoore han fawọn ọba alaye lori bi wọn ṣe fọwọsowọpọ lati le jẹ ki fayawọ dinku, ti iwa jagidijagan nsi lọ silẹ.

O sọrọ yii lakooko to n ṣe ipade pọ pẹlu awọn oniroyin, lori akojọpọ iṣẹ irinju wọn fun odidi ọdun kan, to waye ni ọfiisi wọn, Idiroko. O ni ka ni oun nnkan mi-in lati fi dupẹ lọwọ awọn ọba ọhun fun ẹmi imoore oun ko ba ṣe ju bẹẹ lọ.

Ọga agba naa ṣalaye pe bi oun ṣe tẹwọgba ipo naa lọdun to kọja, loun ṣe ipade pọ pẹlu awọn ọba alaye bii Olu tiluu Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenro, Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Gbadebọ Adedọtun, atawọn mii in, ti wọn si gba oun tọwọ tẹsẹ, tawọn si jọ jiroro lori ọna lati dẹkun iwa fayawọ ati bi ajọṣepọ yoo tun ṣe danmọran laaarin awọn mejeeji.

O ni igba kan tiẹ wa ti Olu Ilaro pe gbogbo awọn Yewa jọ, ti onikakulu si sọ ẹdun ọkan nigba agbegbe wọn lori ẹṣọ aṣọbode tawọn naa si sọ tiwọn, o ni tawọn si gbe igbesẹ loju ẹsẹ.

Ọkunrin naa sọ pe lawọn ẹbẹ wọn tawọn ṣiṣẹ lee lori ni pe kawọn ọmọ ọdọ agbegbe ọhun ni annfaani lati gbawọn ṣiṣẹ aṣobode, eyi to ni awọn ṣi n ṣiṣẹ le lori lọwọ.

Nigba to n ṣiro iṣẹ irinju wọn lati inu oṣu kin- in- ni, ọdun 2021 si oṣu kin-in-ni, 2022, o sọ pe apapọ owo tawọn ri ko jọ ninu awọn nnkan tawọn gba ti wọn tun ta fẹẹ to miliọnu mẹrinlelogoji naira.

O ni apapọ nnkan tawọn ri gba ni apo irẹsi, igbo, ororo atawọn nnkan mii-in fẹẹ to ẹgbẹrun kan ati irinwo.Nigba ti apapọ owo nnkan ti wọn ri gba jẹ biliọnu kan abọ naira.

Bẹẹ lo tun sọ pe idunu lo jẹ foun pe laarin oṣu mẹrin to kọja yii  gbigbogun ti awọn oṣiṣẹ wọn dinku, ti ajọṣepọ to danmọran si n lọ laarin awọn ati araalu.

Dera waa ṣeleri pe ẹṣọ alaabo yoo tubọ maa tẹsiwaju nipa lila awọn araalu lọyẹ lori bi adinku yoo ṣe deba fayawọ, ti ko ni jẹ akoba fawọn araalu.

O tun lo akoko ọhun lati gba awọn obi ati alagbatọ ti wọn gbe lẹnu ọna ẹnu bode Idiroko nimọran lati kilọ fawọn ọmọ wọn ki wọn ye doju ija kọ awọn oṣiṣẹ oun. Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ awọn alaabo yooku lori ifọwọsowọpọ wọn lati dena fayawọ.


 

 

 

 






No comments:

Post a Comment

Pages