Olu Ọmọtọṣọ ni oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu Action Alliance nipinlẹ Ekiti - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 2 February 2022

Olu Ọmọtọṣọ ni oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu Action Alliance nipinlẹ Ekiti


 

 

Ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, nipinlẹ Ekiti, ti fa Olu Ọmọtọṣọ kalẹ gẹgẹ bi oludije gomina ninu ibo to n bọ pẹlu ileri pe oun ni yoo jawe olubori.

 

Nibi ibo ẹgbẹ ọhun to waye ni Ado Ekiti, ni wọn ti fa ọwọ ẹ soke nigba tawọn yooku ti wọn jọ dije juwọ silẹ fun un pe awọn gba ko lọọ ṣoju awọn.Alaga ẹgbẹ ọhun lapapọ, Ọnarebu  Adekunle Rufai Omo-Aje, to ṣaaju awọn yooku ẹ lọ sibi eto ọhun sọ pẹlu idaniloju pe oludije wọn yoo fakọyọ nibi ibo ti yoo waye ọhun ninu oṣu kẹfa ọdun yii.

 

O sọ pe pẹlu igboya loun fi le sọ pe gbogbo  nkan teeyan fi n kun oju oṣuwọn layi di gomina ni oludije awọn ni, ati pe o tun jẹ ẹni tawọn araalu n fẹ tiẹ.

 

Alaga ẹgbẹ ọhun wa gba awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lamọran lati  dibo wọn fẹni to nifẹẹ araalu lọkan, to le ṣe awọn nnkan ti wọn ba n fẹ toun si mọ pe oludije awọn kaju ẹ, ti ko si ni doju ti wọn.

 

Ninu ọrọ  Olu Ọmọtọṣọ, lẹyin ti wọn fa a kalẹ tan, o dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu AA fun anfaani ti wọn fẹẹ fi foun yii pẹlu ileri oun ko nii ja wọn ni tan an mọ.


Ọkunrin  oludije naa ti wọn sọ pe o ti wa ninu ẹgbẹ ọhun lati bi ọdun meloo sẹyin ni wọn sọ pe o ti lo ọgbọn to ni lati jẹ ki itẹsiwaju ba ẹgbẹ ọhun.

 

Ọmọtọṣọ ti waa sọ pe awọn opo ti ẹgbẹ  naa duro lee lori loun yoo  tẹle, o wa rọ gbogbo awọn ti jọ dije, ti wọn juwọ silẹ fun un lati mṣatilẹyin foun, ki wọn jọ ṣiṣẹ pọ ki erongba wọn le di amuṣẹ lati gbajọba ninu ibo to n bọ ninu oṣu kẹfa naa.


No comments:

Post a Comment

Pages