Awọn oṣere tiata barajẹ lori iku Tafa Oloyede - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 2 February 2022

Awọn oṣere tiata barajẹ lori iku Tafa Oloyede


 

Awọn oṣere tiata barajẹ lori iku Tafa Oloyede

Lati ana, ti wọn ti kede pe agba oṣere nni, John Adewumi, tọpọ mọ si Tafa Oloyede, jade lawọn oṣere tiata ti barajẹ lori iku to pa oju ili mọn ọn ka oṣere ọhun de.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, bi ala lo si n jẹ loju awọn ẹlomii-in, papa awọn ti wọn tii ri tipẹ, bẹẹ lawọn kan si n beere lọwọ ara wọn pe ṣe loootọ ni ọkunrin ku.

Ile agba oṣere naa to wa niArowomọle, laduugbo Kajọla, niluu Oṣogbo, ni wọn sọ pe o dakẹ si lẹyin aisan ranpẹ to ṣe e. Ẹni ọdun mọkandinlaaadọrin

Bo tilẹ jẹ pe o ti to bi ọdun meloo kan ti ọkunrin naa ti wa nibu aisan, ṣugbọn igba kan wa ti wọn ni ara ẹ ti ya, to si n bawọn lọ si lokeṣan ibi ti wọn ba a pe si.

Ninu oṣu kejila ọdun to kọja yii lo wa sibi eto kan, ti Kasnaty, sọrọsọrọ ṣe fawọn agba, nibi ti wọn ti fun Alagba Tunbọsun Ọdunsi, ni mọtọ. Odu ni Tafa Oloyede ki i ṣaimọ foloko nidii iṣẹ tiata, ọdọ Oloogbe Oyin Adejọbi, lawọn eeyan si ti gbokiki ẹ ninu iṣẹ to yan an laayo ọhun. Fiimu kan tawọn eeyan tun ti mọ ji ni Akanji Oniposi, bẹẹ lo tun kopa ninu awọn ere tẹlifiṣan atawọn fiimu.

Ọpọ awọn onitiata lo ṣapejuwe ọkunrin ọhun gẹgẹ bi ẹni to nirẹlẹ, Ti ki i fiṣẹ ẹ ṣere. Iyawo atọmọ ni lo fi saye lọ .

 

 

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages