Gbogbo eto lo ti to fun ipade apero gbogbogbo akọkọ fawọn ọba ilẹ Awori, tipinlẹ Ogun, eyi ti Ọlọta tiluu Ọta, Ọba Abdulkabir Adeyẹmi Ọbalenge fẹẹ gbalejo ẹ, ti yoo waye lọjọ kẹjọ si ọjọ kọkanla, oṣu keji, ọdun yii.
Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ wa lọwọ, ipade apero ọhun, ti akori ẹ da lori "Ironu ilẹ Awori lọwọ eto aabo, ijọba tiwa-n-tiwa ati ajakalẹ arun korona’’ ni wọn yoo ṣe ni Crown City Resort, Agbara, nipinlẹ Ogun, bẹrẹ ni deede aago mẹwaa, lojoojumọ.
Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Nọimọt Salakọ-Oyedele, ni alejo pataki ti wọn reti lọjọ naa, nigba ti Akarigbo tilẹ Rẹmọ, Ọba Babatunde Adewale Ajayi, alaga fawọn ọba nipinlẹ Ogun, yoo jẹ oludanilẹkọọ
Lara awọn ti yoo tun ba wọn sọrọ lọjọ naa ni Sẹnetọ Akin Ọdunsi, to ti figba jẹ aṣofin agba nile igbimọ aṣofin niluu Abuja, to ṣoju Ogun West.
Bẹẹ naa ni Ọnarebu Tunji Akinosi, Kọmiṣanna to n ri si awọn nnkan to ṣẹlẹ ninu igbo iyẹn Forestry, ati Ọnarebu Afọlabi Afuwapẹ, toun jẹ kọmisanna fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ogun.
Awọn yooku ti wọn tun bọ lọjọ naa ni Ọjọgbọn Babatunde Salakọ, toun jẹ ọga agba nileeṣẹ Insitute of Medical Research,ati Johnson Kokumo, igbakeji ọga agba patapata fawọn ọlọpaa.
Ọlọta, ti waa ṣeleri pe ipade apero toun fẹẹ gbalejo ẹ yii yoo jẹ eyi ti ko ti i waye nitori gbogbo ọrọ to jẹ mọ ilẹ Awori ni wọn yoo sọ fodidi ọjọ mẹta ọhun.
Oloye Ọlanrewaju Baṣọrun, to jẹ Ṣeriki ilu Ọta, to tun jọ alaga igbimọ to ṣagbatẹru eto ọhun, sọ pe ara ọkan lati jẹ ki gbogbo ọmọ ilẹ Awori wa ni iṣọkan, ti yoo tun wa ọna abayọri sawọn iṣoro ti wọn ti n koju latilẹ.
O tẹsiwaju pe "Igba akọkọ ree, ti iru ayẹyẹ bẹẹ yoo waye nilẹ Yoruba, a si dupẹ pe o waye labẹ Kabiyesi wa, Ọlọta tiluu Ọta’’
Oloye Baṣọrun waa pari ọrọ ẹ pe ọkan lara anfaani lati mu idagbasoke ba ilẹ Awori ni eto ọhun, o tun mu dawọn eeyan loju pe ọkan lara igbe aye ọtun ni eleyii, o ni adura awọn ni pe ki Ọlọrun tubọ maa fun Ọlọta ni ọgbọn ati oye ti yoo fi
Gbogbo eto lo ti to fun ipade apero gbogbogbo akọkọ fawọn ọba ilẹ Awori, tipinlẹ Ogun, eyi ti Ọlọta tiluu Ọta, Ọba Abdulkabir Adeyẹmi Ọbalenge fẹẹ gbalejo ẹ, ti yoo waye lọjọ kẹjọ si ọjọ kọkanla, oṣu keji, ọdun yii.
Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ wa lọwọ, ipade apero ọhun, ti akori ẹ da lori "Ironu ilẹ Awori lọwọ eto aabo, ijọba tiwa-n-tiwa ati ajakalẹ arun korona’’ ni wọn yoo ṣe ni Crown City Resort, Agbara, nipinlẹ Ogun, bẹrẹ ni deede aago mẹwaa, lojoojumọ.
Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Nọimọt Salakọ-Oyedele, ni alejo pataki ti wọn reti lọjọ naa, nigba ti Akarigbo tilẹ Rẹmọ, Ọba Babatunde Adewale Ajayi, alaga fawọn ọba nipinlẹ Ogun, yoo jẹ oludanilẹkọọ
Lara awọn ti yoo tun ba wọn sọrọ lọjọ naa ni Sẹnetọ Akin Ọdunsi, to ti figba jẹ aṣofin agba nile igbimọ aṣofin niluu Abuja, to ṣoju Ogun West.
Bẹẹ naa ni Ọnarebu Tunji Akinosi, Kọmiṣanna to n ri si awọn nnkan to ṣẹlẹ ninu igbo iyẹn Forestry, ati Ọnarebu Afọlabi Afuwapẹ, toun jẹ kọmisanna fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ogun.
Awọn yooku ti wọn tun bọ lọjọ naa ni Ọjọgbọn Babatunde Salakọ, toun jẹ ọga agba nileeṣẹ Insitute of Medical Research,ati Johnson Kokumo, igbakeji ọga agba patapata fawọn ọlọpaa.
Ọlọta, ti waa ṣeleri pe ipade apero toun fẹẹ gbalejo ẹ yii yoo jẹ eyi ti ko ti i waye nitori gbogbo ọrọ to jẹ mọ ilẹ Awori ni wọn yoo sọ fodidi ọjọ mẹta ọhun.
Oloye Ọlanrewaju Baṣọrun, to jẹ Ṣeriki ilu Ọta, to tun jọ alaga igbimọ to ṣagbatẹru eto ọhun, sọ pe ara ọkan lati jẹ ki gbogbo ọmọ ilẹ Awori wa ni iṣọkan, ti yoo tun wa ọna abayọri sawọn iṣoro ti wọn ti n koju latilẹ.
O tẹsiwaju pe "Igba akọkọ ree, ti iru ayẹyẹ bẹẹ yoo waye nilẹ Yoruba, a si dupẹ pe o waye labẹ Kabiyesi wa, Ọlọta tiluu Ọta’’
Oloye Baṣọrun waa pari ọrọ ẹ pe ọkan lara anfaani lati mu idagbasoke ba ilẹ Awori ni eto ọhun, o tun mu dawọn eeyan loju pe ọkan lara igbe aye ọtun ni eleyii, o ni adura awọn ni pe ki Ọlọrun tubọ maa fun Ọlọta ni ọgbọn ati oye ti yoo fi maa tẹ siwaju
No comments:
Post a Comment