Bi a ṣe kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC ipinle Eko, adanu nla lo jẹ fun wọn- Jandor - BO SE RI

Breaking

Saturday 22 January 2022

Bi a ṣe kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC ipinle Eko, adanu nla lo jẹ fun wọn- JandorDokita Ọlajide Adediran, tọpọ awọn eeyan mọ si Jandor, ti sọ pe adanu nla lo jẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC,ipinlẹ Eko,  nitori bi wọn ṣe fẹgbẹ naa silẹ bọ sinu PDP.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, lo sọrọ ọhun lakooko tawọn agba ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣayẹyẹ igbaniwọle fun ọkunrin naa atawọn eeyan ẹ ti wọn jẹ Lagos for Lagos, eyi ti ayẹyẹ naa waye ni TBS, niluu Eko.

O sọ pe pẹlu bi ogo ti n jẹ ti Ọlọrun, bi Gomina Ṣeyi Makinde, tipinlẹ Ọyọ, ṣe wọle lakooko ibo to waye, ti ko sẹni to mọ ọn, bẹẹ naa loun naa yoo ṣe wọle lọdun 2023.

Jandor tun ṣalaye pe akoko ti to tawọn ọmọ ipinlẹ Eko, lati kuro ninu oko ẹru ti APC, ko wọn si lati bi ọdun meloo sẹyin, ki wọn si fi ibo wọn to n bọ le wọn danu.

O fikun ọrọ ẹ pe pẹlu idunnu loun ṣe darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, lati fi le gbakoso Eko, eyi toun nireti pe awọn yoo jọ fọwọsowọpọ lati gbajọba.

Bakan naa lo tun fikun ọrọ ẹ pe ki i ṣe tọrọ ẹnu latigba toun atawọn eeyan ẹ Lagos for Lagos, ti fẹgbẹ ti wọn wa tẹlẹ silẹ ni nnkan ko ti rọgbọ mọ fẹgbẹ APC, ti wọn si n japoro ẹ di oni.

Nibi ayẹyẹ ọhun lawọn agba oṣelu PDP, to fi mọ alaga wọn lapapọ, Iyorchia Ayu, ti wa nibẹ, lati sọ Jandor atawọn eeyan ẹ di ọmọ ẹgbẹ wọn.

Lara awọn to tun wa nibẹ ni Bukọla Ṣaraki,to jẹ olori ile igbimọ aṣofin agba tẹlẹ lorileede yii. Oloye Bọde George, Gomina Ṣeyi Makinde, tipinlẹ Ọyọ, Gomina Okezie Ikpeazu, tipinlẹ Abia.


Awọn Gomina yooku ti wọn tun wa nibẹ ni  Udom Emmanuel, tipinlẹ Akwa Ibom, Dokita Ifeanyi Ugwuanyi, tipinlẹ Enugu ati  Ezenwo Wike, tipinlẹ  Cross Rivers. Bẹẹ naa ni Taofeek Arapaja, Dokita Oluṣegun Mimiko, Dele Momodu atawọn mii-in.q

Ninu ọrọ Ayu, alaga ẹgbẹ naa, lo ti sọ pe ko si aye lati tan awọn ọmọ orileede yii nigba kẹta, atunṣe lo ni wọn sọ pe awọn fẹẹ ṣe ṣugbọn ti wọn sọ ọ di inira nigba ti wọn de ipo tan.

Ṣugbọn Ikpeazu, ni tiẹ ṣapejuwe Jandor, gẹgẹ bi ẹja nla ti àwọ̀n wọn gbe, ti yoo tun mu adun ba ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Eko.

 


No comments:

Post a Comment

Pages