Buhari lo abẹwo rẹ si ipinlẹ Ogun lati yanju idojukọ tawọn eeyan koju- Ṣẹgun Ṣowumi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 13 January 2022

Buhari lo abẹwo rẹ si ipinlẹ Ogun lati yanju idojukọ tawọn eeyan koju- Ṣẹgun Ṣowumi


Ṣẹgun Ṣowumi, ọkan lara agba ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, to tun fẹẹ jade dupo gomina lọdun to n bọ, ti rọ Aarẹ orileede yii, Mohammadu Buhari, lati lo abẹwo ọlọjọ kan to ṣe sipinlẹ naa lati fi yanju awọn ipenija ati idojukọ ti wọn koju.

Ninu atẹjade kan to fi sita, lo ti ṣalaye pe nnkan to dara to si wuyi to le mu ki irinajo aarẹ orileede yii ni itumọ ni to ba lo akoko naa fi wa ọna abayọri iṣoro tawọn eeyan ipinlẹ Ogun fojoojumọ koju yii.

Gẹgẹ bi Agbẹnusọ fun Abubakar Atiku lakooko ipolongo ibo to kọja yii ṣe wi, o ni lara awọn idojukọ ọhun ni ọna Eko si Sango si Abẹokuta, Ọta- Agbara.Bẹẹ naa lawọn ọna Ṣagamu-Ogijo-Ikorodu, to jẹ tijọba apapọ yii lo sọ pe awọn eeyan fojoojmọ ba inira pade to si ti fẹẹ yọ ile aye lẹmi awọn ẹlomi-in.

O ni idunnu ni yoo jẹ ti Buhari ba le fi inu ọkan awọn eeyan balẹ ninu ọrọ to ba sọ pe atunṣe yoo bẹrẹ ni kiakia, koda ko to di pe o pada siluu Abuja.

O tun sọ pe bi ijọba apapọ ba ro pe awọn ọna yii ko le ṣee ṣe ki wọn kuku faa le ijọba ipinlẹ Eko ati Ogun lọwọ, ki wọn wa ọna atunṣe si.

Ọkunrin yii tun ṣalaye siwaju sii pe'' Aarẹ wa, gẹgẹ bi ipinlẹ Ogun, a ni awọn ọna to jẹ ti ijọba apapọ ti wọn wa ninu ewu. Ọna Abẹokuta si Eko lọọ si ọna Ọta, nibi tawọn ileeṣẹ nlanla wa bajẹ kọja sisọ. Mo nigbagbọ pe tijọba apapọ ko ba le ṣe iranlọwọ, a fẹẹ ki ẹ lo aṣẹ ati ipo yin fa wọn le awọn tipinlẹ lọwọ, ki wọn si bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ.''

Ṣẹgun Ṣowumi, tun lo akoko naa lati sọ fun Aarẹ Buhari, lati kilọ fawọn ẹṣọ asobode lori bi wọn ṣe n dẹmi awọn eeyan alaiṣẹ legbodo lawọn ọna to paala paapaa julọ lawọn ilu bii Idiroko, Ilaro, Owode, Ayetoro, Imẹkọ-Afọn ati Ipokia, Ogun West. Ti wọn yoo si maa sọ pe awọn fayawọ lawọn n le.

Bẹẹ lo wa pari ọrọ ẹ nipa di dupẹ lori ti reluwe to lọ si Eko si Ibadan, to n gba Abẹokuta kọja, o waa bẹ lati jẹ ki ala papakọ ofurufu Wasinmi, Abeokuta , di amuṣẹ, eyi to ni yoo tun jẹ ki ọrọ aje orileede yii tun ga soke sii.

 

No comments:

Post a Comment

Pages