E fún Buhari láàyè láti yanjú ìṣòro orílèèdè yìí kó tó gbéjọba sílẹ̀-Salvador - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 8 January 2022

E fún Buhari láàyè láti yanjú ìṣòro orílèèdè yìí kó tó gbéjọba sílẹ̀-Salvador


Moshood Salvador , ọkan lara agba oṣelu ninu ẹgbẹ APC, nipinlẹ Eko, to tun jẹ aṣaaju ikọ Conscience, ti gba awọn to sunmọ aarẹ orileede yii, Mohammadu Buhari, nimọran lati fun un laaye lati lo iwọnba to ku ninu iṣakoso ẹ lati fi yanju awọn iṣoro to koju wa.

O sọrọ yii lakooko to ba awọn oniroyin sọrọ lọsẹ to kọja, nibi ayẹyẹ ibẹrẹ ọdun ti ikọ naa ṣe niluu Eko, o sọ pe o yẹ ki wọn jẹ ko fọwọ si iwe abadofin ọdun 2021, eyi ti yoo fopin si ọna idibo wa lorileede yii.

Ọkunrin naa sọ pe Aarẹ gbọdọ fi apẹẹrẹ rere lelẹ fawọn iran to n bọ, to ba le kọwọ bọ iwe eto idibo naa, bẹẹ lo tun lo akoko naa lati gba aṣofin lamọran lati yọ ibo gbangba lasa n ta kuro niwọngba ti Aarẹ ti tako.

 Salvador  tun sọ pe atunto eto idibo yii yoo jẹ isakoso rere waye lorileede yii. Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn araalu fẹẹ ki wọn ka ibo wọn ṣugbọn o ṣe awọn laaanu pe awọn rọwọ awọn eeyan kan ti wọn ko fẹ jẹ ki Aarẹ fọwọ si abadofin naa.

 O ni awọn eeyan ti wọn ko fẹ ki kinni ọhun ṣe e ṣe wọn ko sọrọ nipa igbesẹ tuntun naa. O ni awọn ni lati gba Buhari lamọran lati tẹle ijọba tiwa-n-tiwa, nitori awọn le ri esi rere lati ọdọ awọn araalu.

 Agba oṣelu ọhun tun ṣalaye ṣiwaju pe “Igbesẹ tuntun lati dibo yii ni yoo fopin si eeru, ti yoo si yatọ si ti atijọ, ti ko ṣiṣẹ, ti yoo si jẹ kawọn oṣiṣẹ eleto idibọ mọ nnkan ti wọn n ṣe, nitori awọn ti wọn ki ka ibo wọn nigba ti ibo ba waye, pẹlu ofin yii yoo jẹ ki jibiti kuro’’

 “Nigba ti nnkan wọnyii ba waye ko ni si wahala lori dida ẹmi legbodo, bi ba dukia jẹ bẹẹ ni jibiti naa yoo dinku. Abadofin yii ko nii jẹ kawọn ẹgbẹ oṣelu maa fi dandan le ibo gbngba lasa n ta’’

Bẹẹ lo tun rọ Aarẹ Buhari lati ri pe o mu ileri to ṣe fawọn eeyan ṣẹ, nitori ara nni awọn araalu  gan-an ni. O ni ko lo oṣu mejidinlogun to ku ninu ijọba ẹ lati fi yanju ipenija ti wọn koju lorileede yii.

No comments:

Post a Comment

Pages