Aṣofin Tolu Ọdẹbiyi, to n ṣoju ẹkun Ogun West, nile igbimọ aṣofin niluu Abuja, ti ke si gbogbo awọn ọmọ orileede yii ki wọn yẹra fawọn nnkan to le arun korona ati eyi ti wọn lo tun ṣẹṣẹ gbode ti wọn pe ni Omicron lede oyinbo lakooko ọdun to n lọ lọwọ yii.
Oloṣelu ọhun ṣekilọ naa tun jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, nipinlẹ Ogun, ṣekilọ ọhun ninu iṣẹ ọdun to ran sawọn eeyan, o ni oun to lẹtọọ to si dara kawọn eeyan tete lọọ gba abẹrẹ lati le dena aisan ọhun.
O rọ awọn eeyan loti lo ọdun keresi yii lati fi sunmọ Ọlọrun, ki wọn si gba ẹkọ ti ọdun ti wọn maa n ṣe lọdọọdun naa fi kọ wa. O sọ pe oun nigbagbọ pe pẹlu adura orileede yii yoo bori gbogbo ipenija ti wọn n koju lati ẹyin wa.
Aṣofin Ọdẹbiyi tun sọrọ siwaju pe ‘’ A gbọdọ wa opin si, arun korona ati eyi to tun ṣẹṣẹ jade ti wọn pe ni Omikirọọnu, ti wọn sọ pe oun naa ti n tan kalẹ kaakiri agbaye. Bẹẹ mo tun rẹ wa lati fọwọsowọpọ ki a wa opin si ipenija taa n koju lori eto abo lakooko yii’’.
O waa lo akoko naa lati ba awọn ọmọ orileede yii ṣajọyọ ọdun tuntun, ki wọn si jẹ ki ifẹ, iṣọkan ati alaafia ko jọba gẹgẹ bi Jesu ṣe fi lelẹ fun ayajọ ọjọ naa. O tun wa lo akoko naa lati fi ran awọn eeyan Ogun West, leti pe oun yoo tẹsiwaju lati maa ran awọn eeyan ẹ yii lọwọ fun imayedẹrun wọn.
No comments:
Post a Comment