Oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu AAC nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Adeyẹmi Harrison, ti ke si awọn ọdọ nipinlẹ naa lati ma ṣe fa sẹyin lori idagbasoke nitori iṣẹ pọ fun wọn lati ṣe.
O sọrọ yii ninu iṣẹ ikinni ku ọdun keresimesi to fi sita, o ni bawọn ọdọ ba ni ẹmi iṣọkan ati ifẹ o da oun loju pe gbogbo nnkan ni yoo maa lọ nirọwọ rẹsẹ.
Ọkunrin naa tun ṣalaye pe, ogo orileede ati ipinlẹ lawọn ọdọ jẹ idi niyii lo ṣe yẹ ki wọn maa wa ọna bi yoo ṣe maa ṣaaju ninu ohun gbogbo paapaa julọ nidii oṣelu.
Ọnarebu Adeyẹmi to ti figba kan jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin, to ṣoju ẹkun Ogun Waterside, nipinlẹ Ogun, tun sọ pe gbogbo wa la mọ pataki ọdun keresi, idi niyi ti gbogbo wa fi gbọdọ wa ni ifẹ ati isọkan.
O sọ pe ‘’ Mo ki gbogbo wa ku ọdun keresi to wọle yii, mo fẹẹ ka ṣe ohun gbogbo bi agbara wa ba ṣe to, ki a ma ṣe ju agbara wa lọ, ki a si tun lo akoko naa lati nawọ ifẹ si awọn to ba ku diẹ kaato lawujọ.’’
‘’Mo tun lo akoko yii lati fi rọ awa ọdọ lati ma ṣe rẹwẹsi nidii oṣelu, nitori, awa ni ogo ọjọ iwaju, idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ Ogun, ọwọ waa ni o wa, ko si yẹ ki a maa woran ki nnkan fi bajẹ tan””
Ọkunrin yii fikun ọrọ ẹ nipa erongba ẹ lati di gomina lọdun 2023 , labẹ ẹgbẹ oṣelu AAC, o ni lati wa atunṣe sawọn nnkan to n ba awọn eeyan ipinlẹ Ogun finra, o sọ pe oun ko sọ pe awọn ti wọn ti jẹ ati ẹni to wa nibẹ ko sagbara tiwọn, ṣugbọn gẹgẹ bi ọdọ, oun fẹẹ lo ọgbọn ati iriri oun lati tubọ mu idagbasoke ba ipinlẹ Ogun.
O ni bi wọn ba le fun oun laaye oun ṣetan lati mu awọn eeyan ipinlẹ yii delẹ ileri, o wa lo akoko naa fun ifọwọsowopọ awọn araalu nigba ti akoko naa ba to.
O ni ẹgbẹ AAC jẹ ẹgbẹ araalu ti ki i figba bọkan ninu, ati pe igba aye irọrun ati alaafia lo jẹ awọn logun. O wa ṣadura pe nigba ti yoo ba fi di ọdun to n bọ, nnkan yoo tubọ ti bọ sipo si rere.
No comments:
Post a Comment