Aarẹ ẹgbẹ OPC New- Era, Oloye Rasak Arogundade Balogun, ti rọ ijọba orileede yii, lati fopin si ẹgbẹ okunkun ti wọn fẹẹ maa ko wọ awọn ileewe girama lakooko yii, nitori atubọtan ẹ ko le so eṣo rere.
Ọkunrin yii sọrọ naa ninu iwe apilẹkọ kan to ka nibi ayẹyẹ ọdun ogun ajọbọ, to waye lọgba ileewe alakọọbẹrẹ Ansar-ud-deen, Makun, niluu Ṣagamu.
O sọ pe bi ẹgbẹ okunkun ṣe fẹẹ ma gbilẹ laarin awọn ọmọ ileewe girama lẹnu ọjọ mẹta yii ki i ṣe nnkan to bojumu, kijọba si tete wa nnkan ṣe si nitori aabo awọn ọmọleewe.
Aarẹ ẹgbẹ naa wa kaanu bi wọn ṣe da ẹmi ọmọ ọdun mejila kan, tileewe Dowen College, legbodo nitori to kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.
Bẹẹ nipa iṣẹlẹ to waye niluu Edo, nibi ti akẹkọọ ti lu tiṣa pa, o lawọn nnkan wọnyii ko yẹ ko maa ṣẹlẹ lawọn ileewe girama, idi niyii ti ijọba apapọ ati tipinlẹ gbọdọ tete gbe igbesẹ to lagbara.
Bakan naa ni Aarẹ ẹgbẹ OPC tun fi aidunnu wọn han lori ipo ti orileede yii wa nipa eto aabo, wọn o fihan gbangba pe ijọba to wa lode yii ti kuna patapata lori ẹtọ ọmọniyan.
O sọ pe awọn ọmọ orileede yii ti n kabamọ lori iṣejọba Muhammadu Buhari, lori bi ijinigbe, apaayan, ifiẹmisofo to n lọ kaakiri, eyi ti ko fi ọkan awọn araalu balẹ rara.
Bẹẹ lo fi aidunnu ẹ han si ipo iha tawọn aṣaaju Yoruba kọ lori awọn nnkan to waye lakooko yii, ti wọn si fẹẹ maa fi oṣelu ba nnkan jẹ. O wa rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii paapaa awọn Yoruba lati wa ni irẹpọ, ki wọn si jẹ ki alaafia jọba.
Nigba to n sọrọ nipa ayẹyẹ ogun ajọbọ ti wọn ṣe lọjọ naa, Ọkunrin naa sọ pe ipa ti Ogun ko ninu iran Yoruba ko ṣe e fọwọrọ sẹyin ati pe ọkan lara awọn ooṣa to ko ṣe fọwọrọsẹyin ni.
O ni bo tilẹ jẹ pe igba akọkọ ree ti wọn yoo wa ṣe iru nnkan bẹẹ nipinlẹ Ogun, awọn si ti pinnu pe ọdọọdun lawọn yoo maa gba kaakiri ipinlẹ naa.
Arogundade tun sọ pe awọn ṣeranti Ogun ajọbọ gẹgẹ bi awọn ẹlẹsin musulumi ati kkristẹẹni, ṣe maa n ṣajọyọ, nitori awọn ko le fọrọ ẹ ṣere, bawọn ẹlẹsin ibilẹ ko ṣe e fi ṣere.
No comments:
Post a Comment