Gbajumọ olorin ẹlẹsin Islam nni, AlaajaRuqayat Gawat Oyefẹsọ, ko le tete gbagbe ọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, ki i ṣe fun nnkan mii in bi ko ṣe ayẹyẹ onibẹta to ṣe e, ti wọn si tun fun un ni kọkọrọ mọto olowo nla.
Ayẹyẹ ọhun to waye ni White Stone Event Center, Billings Way, Orẹgun, Ikẹja, niluu Eko, lawọn eeyan jankanjankan ti peju pesẹ lati wa ba a ṣajọyọ ayẹyẹ ọhun naa. Bi obinrin olorin Islam ti ṣe ifilọlẹ kasẹẹti tuntun, bẹẹ lo tun ṣe ayajọ imọlẹ, to tun wa lo akoko yii lati fi ro awọn eeyan lagbara.
Pambabari ẹ ni mọto bọgini olowo nla ti Anọbi Muṣin fi ta a lọrẹ, eyi to tun mu ori awọn eeyan wu lọjọ naa. Lara awọn to wa nibẹ ti wọn tun fere da awọn eeyan lọla ni awọn olorin Islam ẹgbẹ ẹ bii Alaaji Wasiu Kayọde As-Sidik, Alaaja Misturah Amọke, Aderounmu Ashafa Teminisuccess, Alaaja Aminat Babalọla Omotayebi, Alaaja Tawakalitu Adunni Oloriire, Alaaji Abdulkabir Alayande, Ere Asalatu, nigba ti Saidi Oṣupa naa yọju ṣugbọn ti ko pẹ to fi kuro nibẹ.
No comments:
Post a Comment