Ọba oniba ṣayẹyẹ ọdun kan lori itẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 9 December 2021

Ọba oniba ṣayẹyẹ ọdun kan lori itẹ


 Kabyiesi, Alayeluwa, Ọba (Dokita) Sulaimon Adeṣina Raji – Ashade, to jẹ Oniba of tiluu lba, Oniba Ẹkun, llufẹmiloye, ti sọ pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun, nitori oun ko mọ pe oun yoo dori ipo naa.

 

Ọba naa sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ fun ayajọ ọdun kan, to gori oye, nibi to ti mẹnuba awọn aṣeyọri ẹ lẹnu igba to di ori ade ili naa.

 

O ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fawọn ohun ribiribi to to waye latigba toun ti gba iwe ẹri gẹgẹ bi ọba lọjọ keje, oṣu kejila, ọdun to kọja, lọwọ Gomina ipinlẹ Eko.

 

 O ṣalaye lẹkunrẹrẹ lori  awọn aṣeyọri ẹ yii bii ṣiṣe awọn ọna bii ọna Igbeyinadun,  Ashade, Oke - Odan. Nipa ilera, o ni  wọn kọ ibi ilera iyẹn Health Centre, pẹlu irinṣẹ ti wọn si faale ijọba lọwọ.

 

Bẹẹ lo tun sọ pe awọn ti tun ileewe ṣe, ti igbesẹ si n lọ lọwọ lori ileewe girama fun ilu lba, ti ijọba si ti fi ontẹ lu fun Ọba lati kọ. Awọn tun pese lCT Center, pẹlu awọn ẹrọ ayara bi aṣa (computers).

 

Kabiyesi tun fi kun ọrọ ẹ pe ipese ẹrọ amunawa, tiransifọm 500kv ati ina oju ọna fun aabo to peye. O ni awọn ra ilẹ eekan mejidinlọgbọn lati fi kọ ọja igbalode, ileewe girama, ibupa ẹran. O ni  kikọ ati ṣiṣe iranlọwọ owo fun ẹsin mẹtẹẹta , musulumi, kirisitẹẹni ati ẹsin ibilẹ.

 

Bakan naa lawọn ko fi eto idajọ sẹyin laaarin ọdun kan naa yii,nipa kikọ  kootu majisireeti mej fun ilu lba, eyi to sọ pe o ti de ipele ile kikan.

 

 Lara awọn ohun ti Ọba Sulaimon tun gbese , riro awọn ọdọ lagbara, iranwo fun awọn ọlọja , gbigbe aṣa Yoruba larugẹ atawọn nnkan mii in.

 

O waa dupẹ fun aduroti awọn aṣeyọri wọnyii. O tẹsiwaju pe ilu lba, ti wa tipẹ, Oba Alade lba, jẹ ninu awọn ọba akọkọ ( First class Oba). Ayẹyẹ yii  ni wọn lo sọ pe o ti bẹrẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kọkanla, ti yoo si pari lọjọ kẹrinla oṣu yii.

 

O dupẹ lọwọ gbogbo oloye Iba, awọn igbimọ ayẹyẹ ọdun kan, gbogbo araalu, pataki julọ awọn oniroyin fun aduroti wọn.

No comments:

Post a Comment

Pages