Fun erongba ẹ lati jẹ ki Alafia to peye wa fawọn eeyan ẹ ni Ogun West, Aṣofin Tolu Ọdẹbiyi, to n ṣoju ẹkun Ogun West, nile igbimọ aṣofin niluu Abuja ti ṣeto ayẹwo oju ati fi fawọn eeyan agbegbe naa ni gilaasi oju lọfẹẹ. Eyi ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun ati Ogunjọ, oṣu yii.
Gẹgẹ bi atẹjade tawọn oluranlọwọ iroyin fun ọkunrin naa gbe jade lana an, ni wọn ti ṣalaye pe eto ọhun yoo waye pẹlu ajọ ẹ, ti wọn pe ni Tolu Odebiyi Foundation ati ajọṣepọ pẹlu ile iwosan Federal Medical Centre, to wa ni Joga-Orile, nipinlẹ Ogun.
Ayẹwo oju ni yoo kọkọ waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii nigba ti iṣẹ abẹ yoo waye logunjọ, oṣu yii lọgba ile iwosan naa. Wọn ni erongba wọn ni pe gẹgẹ bi a ṣe mọ pe oju ni imọlẹ ara, wọn ko fẹẹ ki abawọn de ba oju awọn eeyan agbegbe naa, ki wọn si tun ni ilera to peye.
No comments:
Post a Comment