Mo ṣetan lati lọọ ṣoju Ogun Central niluu Abuja lẹẹkeji- Sẹnetọ Ọbadara - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 14 March 2022

Mo ṣetan lati lọọ ṣoju Ogun Central niluu Abuja lẹẹkeji- Sẹnetọ Ọbadara


Sẹnetọ Gbenga Ọbadara, to ti figba kan jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju niluu Abuja, fun ẹkun Ogun Central, ti sọ pe oun ti n gbaradi lati jade dupo naa lẹẹkeji, fun ibo to n bọ lọdun 2023.

O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ, o ni oun ti kan sawọn to yẹ koun ba a sọrọ nipa erongba oun yii ati pe idunnu lo jẹ foun pe gbogbo awọn toun ti ba a sọrọ ni wọn fi idunnu wọn han.

O sọ pe ki i ṣe pe oun ṣẹṣẹ ṣe e ati pe ni gbogbo igba toun fi kọkọ wa nibẹ, ko si wọọdu kan agbegbe Ogun Central, toun ko ṣiṣẹ aritọka si nibẹ, ti wọn si waa di akoko yii.

Nitori idi eyi ko si ibẹru foun rara oun si nigbagbọ pe ti wọn ba foun ni tikẹẹti lati dije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ogun, oun ko nii jawọn eeyan oun nitanmọ ọn.

Bakan naa lo tun mẹnuba nipa erongba Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lati di aarẹm ọkunrin to jẹ alakoso fẹgbẹ to ni erongba nilẹ Yoruba, iyẹn South West Agenda, SWAGA, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ẹni ti ara ko ba ya, ti alafia ẹ ko ba pe, ko le rin awọn irin ri oludije ọhun naa rin lakooko yii.

Ọkunrin to ti figba jẹ aṣoju nile igbimọ aṣofin niluu Abuja, fun ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, tun ṣalaye pe ni nnkan bi ọsẹ meji si akoko yii ni Aṣiwaju yoo pe aadọrin ọdun, o ni sibẹ ara si da pepe, lati ibikan sikeji, lo n lọ lati fi  erongba  ẹ han, tawọn eeyan si n tẹwọgba.

O ni ka yọwọ oṣelu kuro ta ni ẹni to tun le di aarẹ orileeede yii, to kun oju oṣuwọn bi ko ṣe Aṣiwaju Tinubu, ati pe titi di akoko yii ko ta tun ni wọn ri to jade sita, tabi lọọ kaakiri pe oun fẹẹ jade dupo.

Ọbadara waa sọ pe nnkan to tootọ, to si yẹ ni pe ki gbogbo awọn eeyan gbarukutu ti ọkunrin ọhun ki awọn erongba ẹ ati ala ẹ ko le di mimuṣẹ. Bẹẹ lo tun sọ pe pẹlu gbogbo awọn ibi ti ẹgbẹ wọn SWAGA, ti de, o ti han daju pe ko si ipinlẹ naa lorileede yii ti wọn ko nifẹẹ Tinubu.

O tun ṣalaye pe “ Ṣe ẹ mọ pe lakooko oṣelu, ko si isọkusọ tawọn oloṣelu ko le sọ, iyẹn ko si le mu ifaṣẹyin ba wa rara, ẹni ti ara ẹ ko baa da pe ko le rin iru irin ti Aṣiwaju rin, gbogbo iyẹn ko kan wa, a ti mọ pe oriṣiriṣi nnkan ni wọn yoo maa sọ lakooko yii, iṣẹ tiwa si n tẹsiwaju’’

Nigba to n dahun lori bawọn kan tun ṣe gbe Igbakjeji aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, dide lati dupo aarẹ, Sẹnetọ Ọbadara sọ pe, ko si ẹni ti nnkan gidi ko wuu ati pe aye ijọba tiwa-n-tiwa, ni a wa yii, onikaluku lo le ṣe nnkan to ba wuu, ṣugbọn ti Aṣiwaju tawọn gbe dani yii, awọn nigbagbọ pe yoo ṣe eṣo rere.

 


No comments:

Post a Comment

Pages