Ọlọrun lo ran Ọba Kẹhinde Olugbenle siluu Ilaro-Ọgbẹni Kẹhinde Awotọna - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 4 December 2021

Ọlọrun lo ran Ọba Kẹhinde Olugbenle siluu Ilaro-Ọgbẹni Kẹhinde Awotọna


 Ọgbẹni Kẹhinde Awotọna to jẹ oludari ileeṣẹ burẹdi iyẹn ‘’Praise God Bakery’’ to tun jẹ akọwe fẹgbẹ awọn oniburẹdi niluu llaro, Yewa, ti ṣapejuwe Ọba Kẹhinde Gbadewọle Enoch Olugbenle, Olu Ilaro, gẹgẹ bi ẹni ti Ọlọrun ran bi akanda eda.

Ọkunrin yii sọrọ naa lakooko to n ki Ọba naa fayẹyẹ ọjọọbi ẹ, ọdun mẹrinlelaadota. O sọ pe bi a ba wo ọna ti wọn gba bi ọba alade ọhun ati bo ṣe di ọba, pelu awọn ldagbasoke to ti mu wọ llaro ati ilẹ Yewa, laaarin ọdun mẹwaa to ti gori lte, o fihan pe Akanda Ọlọrun ni.



Akọwe fẹgbẹ awọn oniburẹdi waa gbadura pe ki ẹmi Ọba naa gun ninu ọwo, ọla ati ldẹra, ki ade si pẹ lori, ki bata pẹ lẹsẹ ki  ẹsin ọba je oko pẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages