Abdul Samad Rabiu, ASR Afrika gbe biliọnu meji abọ naira fun ijọba ipinlẹ Ogun fun idagbasoke ilera - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 26 November 2021

Abdul Samad Rabiu, ASR Afrika gbe biliọnu meji abọ naira fun ijọba ipinlẹ Ogun fun idagbasoke ilera 

Lati le jẹ ki irọrun tun de ba eto ilera ni ileewosan yunifasiti Ọlabisi Ọnabanjọ, eyi to jẹ tijọba ipinlẹ Ogun, ẹlẹyinju aanu kan, Abdul Samad Rabiu, ti gbe biliọnu meji abọ naira kalẹ fun ijọba lati le fi kọ ọsibitu iya atọmọ sinu ọgba ileewosan naa.

 

Nigba to n fi lẹta owo naa le Gomina Dapọ Abidun, tipinlẹ Ogun, lọwọ, niluu Abẹokuta,  Ọgbẹni Ubon Udoh, to jẹ ọga agba fun ASR Africa ọhun, sọ pe igbesẹ yii jẹ ọkan lara ọna ti Abdul Samad Rabiu, oludasilẹ ati alaga BUA Group,lo lati fi ko ipa tiẹ fun orileede Nigeria ati ilẹ Africa.

 

O fikun ọrọ ẹ pe afojusun ọga wọn yii ni lati rii pe awọn ileewosan lawọn ileewe giga yunifasiti dun un wo, wọn si ni awọn ohun eto ilera to ṣe e mu yangan lawujọ. O ni ṣiṣe atilẹyin fawọn fawọn ile eto ilera tawọn ṣe yii ni ipinlẹ Ogun atawọn mẹta mii in wa, ti wọn gbero ninu ọdun yii lati ṣiṣẹ le e lori. ASR yoo tubọ

 

Bakan naa lo sọ pe awọn nigbagbọ pe pẹlu biliọnu meji abọ naira, erongba wọn yoo ri bawọn ṣe n fẹ lati fi le pari kikọ ọsibitu iya ati ọmọ lọgba ileewe iwosan yii. Bẹẹ lo wa sọ pe gbogbo igba ni ASR Afrca yoo  tubọ maa ṣatilẹyin lati le jẹ ki ilera awọn eeyan jẹ ọkunkundun ti yoo si mu adinku ba iṣoro tawọn araalu maa n koju .

 

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun, Gomina Dapọ Abiọdun, dupẹ lọwọ ASRAfrica Initiative, ati oludasilẹ ẹ, Abdul Samad Rabiu, lori bi wọn ṣe n tẹsiwaju atilẹyin igba gbogbo fawọn eeyan ipinlẹ Ogun, pẹlu akiyesi pe gbogbo igba nijọba n wa ọna bi eto ọrọ aje yoo ṣe maa lọ soke si paapaa julọ nipa eto ilera.

 

O fikun ọrọ ẹ pe ileewosan ASR fun iya atọmọ jẹ eyi ti yoo jẹ oore-ọfẹ nla fawọn araalu lati wa maa gba iwosan loorekoore ati pe ijọba oun yoo tubọ sagbara lati rii pe irọrun lawọn ni ilera awọn eeyan yoo maa ba de.

 

 

A gbọ pe afojusun idasilẹ ASR Africa Initiative yii wayẹ lọdun 2021,lati wa ọna abayọri si iṣoro to n koju awọn eeyan ilẹ Afrika lori ilera, eto-ẹkọ ati idagbasoke. Eyi ti wọn si ti n ṣaseyọri ẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages