Bi wọn ba n sọ nipa awọn oṣiṣẹ alaabo to ṣe fi i ṣe awokọṣe rere laarin awọn akẹgbẹ wọn, ta a tun le pe ni ọmọ Yoruba atata, ọkan ni Oyegunlẹ Kọlawọle Joseph, to jẹ ọkan lara ọga alaabo So- Safe.
Bo tilẹ jẹ pe ohun ti mo fẹẹ sọ yii le ma jọ awọn kan loju ṣugbọn mo mọ kinni kan daju pe ọpọ ninu awọn ti wọn jẹ alaabo ilu, tabi ti Ọlọrun ti gbe si ipo kan ni wọn ki i mọ pe adanwo nipo ti wọn wa, ohun ti wọn ba ṣi ṣe ojoojumọ ni akọsilẹ ẹ yoo maa wa.
Boya ki n kuku sọ pe boya lara idanilẹkọọ ti ọga agba awọn So-Safe Corps, Ṣọji Ganzallo, fawọn ọmọ lẹyin ẹ lawọn naa n lo nibi gbogbo ti wọn da de.
Ọkunrin Kọlawọle Oyegunlẹ, to jẹ ọga So Safe ni ọfiisi wọn ti wọn pe ni Abẹokuta East, ni tilẹ ti Ọlọrun, mi o mọ ọn ri, bawo ni mo tiẹ ṣe fẹ mọ ọn nigba to jẹ pe oluuleṣẹ wọn ni mo maa n lọ, ti wọn ba ni iroyin fun wa.
Ṣugbọn lọjọ Tọsidee, ana yii, ọkunrin ti ọfiisi wọn wa ni Ọlọrunṣogo, ti ko jinna si ọfiisi awọn APC, jọ mi loju. Ṣebi ẹnikan lo fẹ fọwọ ọla gba wa loju, ta a gbe iṣẹ fun, ti ko ṣe e, to tun fẹẹ parọ ole mọ wa.
Ero ọkan wa ni pe ki awa naa jẹ ko mọ pe wọn ki i fiya jẹ eeyan gbe, awa naa leeyan, bi a ṣe de ọfiisi, ọtọ ni nnkan ta a ba lọ, ọtọ ni nnkan ta a ba, bi a ṣe ko alaye, ta a ro.
Ka ni awọn ọga mii in ni bi owo yoo ṣe jade lapo ẹni to wa fẹjọ sun ni yoo kọkọ maa wa, Kọlawọle ko ṣe bẹẹ o, ki i si ṣe pe o mọ mi tabi mọ iṣẹ ti mo n ṣe.
Ọrọ tutu lọkunrin yii fi pade mi lati jẹ ki n mọ nnkan ti wọn pe ni aye, koda, ṣe ni gbogbo ibinu yẹn rọ ninu wa ta a ni a ko ṣẹjọ mọ. Ọga yii ni rara o, awọn gbọdọ ṣe iṣẹ awọn, iyẹn lẹkọ akọkọ ti a kọ.
Kaka ki ọga yii ni kawọn ọmọọṣẹ ẹ tẹlẹ wa, funra ẹ lo tẹle wa, eyi to tun wa ya mi lẹnu ju ni pe oun gan-an lo tun sanwo mọto, ẹ gbọ, ọga alaabo meloo lo le ṣe iru ẹ.
Bi ẹni ti wọn fẹẹ mu tun ṣe fẹẹ maa lo agidi, to fẹẹ maa yẹyẹ ọga yii nita gbangba, suuru lo lo, ko tiẹ jẹ kawọn ọmọ ẹyin ẹ to tẹle wa da a si pẹlu bi inu ṣe n bi awọn to
Lọrọ kan ọga yii lo ọgbọn lati fi yanju gbogbo ẹ laigba kọbọ, nitori ẹ ni mo ṣe sọ pe bi iru ọkunrin yii ba pọ ninu iṣẹ abo ilu nnkan yoo tubọ maa dara si ni laaarin ilu.
Lọrọ kan ẹ ba mi gboṣuba nla fun ọkunrin yii gẹgẹ bi ọmọ Yoruba atata, iru wọn la n fẹ niluu lakooko yii. Bẹẹ naa la tun ki ọga wọn, Ṣọji Ganzallo pe awọn ọmọ ẹ n fi apẹẹrẹ rere lelẹ lawujọ.
No comments:
Post a Comment