Ayẹyẹ ayajọ aṣa; Wọn lojoojumọ lo yẹ ki a maa gbe aṣa wa ga nilẹ Yoruba - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 25 November 2021

Ayẹyẹ ayajọ aṣa; Wọn lojoojumọ lo yẹ ki a maa gbe aṣa wa ga nilẹ Yoruba 

Wọn ti gba gbogbo ọmọ kootu-ojiire lamọran lati maa gba aṣa wa ga ni gbogbo igba kawọn iran to n bọ lọjọ iwaju le ri nnkan ba, ko si maa jẹ ohun itiju.

 

Ọrọ yii waye nibi ayẹyẹ ayajọ aṣa, eyi ti wọn ṣe ni gbọngan Blue Roof, lọgba LTV, niluu Eko, lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii. Ohun ti akori tọdun yii da lori ni Lilo awọn ohun ajogunba wa lati ṣe a gbe dide ọrọ aje wa.

 

Eto ọhun to waye pẹlu ajoṣepọ ileeṣẹ to n ri si irinajo igbafẹ, aṣa ati isẹmbaye, nipinlẹ Eko, ni aarẹ ati oludasilẹ  ayajọ aṣa, Ọmọọba Ọlaniyi Ọyatoye, tawọn eeyan mọ si Baba Aṣa , ti sọ pataki ti a fi gbọdọ gbe aṣa ilẹ Yoruba ga lagbaaye. O dupẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Eko , Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu fun ifọwọsowọpọ ẹ lori eto yii.

 

Wọn mẹnuba awọn ọna ta a le gba fi gbe ọrọ aje wa soke nipasẹ awọn ohun iṣẹ ọna, alumọni, ibudo igbafẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọlaniyi wa ke gbajare lori ibudo iro ọdọ lagbara.  O sọ pe  miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira,  iranwọ lati ọdọ ijọba ati awọn ọmọ Yoruba atata.

 

Iyaafin Uzamat Akinbile – Yusuf, to ṣoju Gomina ipinlẹ Eko, sọ bi a ṣe le ti pasẹ aṣa pese iṣẹ lọpọ yanturu fawọn ọdọ ati itẹsiwaju eto ọrọ aje to muyanlori .

 

Kọmiṣanna wa dupẹ lọwọ alakoso eto , Baba aṣa, fun gbigbe eto yi wa si ilu Eko , lẹyin ti wọn ti ṣe mẹrin niluu Canada. O si sọ pe ljọba lpinlẹ Eko yoo ṣa ipa iranwọ fun kikọ ibudo naa.

 

Lara awon alejo Pataki to wa nibẹ, to tun sọrọ ni Erelu. Oloye Abiọla Dosunmu, o sọ bi aṣa Yoruba ṣe gbayi kaakiri aye, o ni a gbọdọ mura lati rii pe o n gberu sii, ko si gbọdọ parun.

 

Ojọgbọn Ọladipupọ Ajiboye lati Fasiti Eko,  ṣalaye aṣa Yoruba gẹgẹ bi eyi to rẹwa pupọ, paapa julọ ede Yoruba, tawọn ara oke -okun si ti wa n kọ.

 

Awọn lgbakeji Gominalati ipinlẹ Ọyọ, Ogun ati Ondo.Bẹẹ lawọn lọbalọba, Baalẹ , eeyan Pataki peju pesẹ sibi ayẹyẹ naa.

1 comment:

  1. Free Baccarat - How to play Baccarat in South Africa
    Free Baccarat. Betting in the online world requires understanding how to play kadangpintar the game septcasino without ever 바카라사이트 learning to use the lingo. It is important to

    ReplyDelete

Pages