Ẹ ma jẹ kawọn fayawọ ba oruko gidi tilẹ Yewa ti ni jẹ o-Ọga aṣobode ipinlẹ Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 24 November 2021

Ẹ ma jẹ kawọn fayawọ ba oruko gidi tilẹ Yewa ti ni jẹ o-Ọga aṣobode ipinlẹ Ogun.Dera Nnadi, ọga awọn aṣọbode kọsitọọmu nipinlẹ Ogun, ti rọ awọn ọba alaye nilẹ Yewa, lati ma ṣẹ jẹ kawọn fayawọ ba orukọ ati apẹẹrẹ rere ti wọn ti ni tẹlẹ jẹ, nitori bi wọn ṣe sọ wọn lorukọ buruku ti wọn ko jẹ.

Ọga agba naa sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ lori awọn ẹru ofin tọwọ wọn tẹ latọdọ awọn onifayawọ. O sọ pe iroyin bi wọn ṣe fẹẹ ma sọ ilẹ naa lẹnu lori iwa tawọn onifayawọ n hu, jẹ eyi to ba ni lọkanjẹ pupọ. Ọkunrin naa sọ pe gbogbo idunkoko awọnn fayawọ ati bi wọn ṣe pe meji ninu awọn oṣiṣẹ oun, ko le mu irẹwẹsi bawọn, nitori ojoojumọ lawọn n gbaradi fun iṣẹ tawọn yan laayo ọhun.

O wa gbogbo iroyin awọn onifayawọ yii bi wọn n ba nnkan jẹ ti wọn si n dẹmi awọn eeyan legbodo le jẹ ki awọn onileeṣẹ nla nla ti wọn ba fẹẹ wa da iṣẹ ṣilẹ lawọn agbegbe ọhun maa roo lẹẹmeji ki wọn to gbe igbesẹ.

Nigba to sọ nipa awọn aṣeyọri ẹ lati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, to gba akoso gẹgẹ bi ọga agba awọn aṣọbode,o sọ pe apapọ owo nnkan tawọn ri gba jẹ miliọnu lọna aadọjọ le ẹgbẹrun mẹta naira.
Lara awọn nnkan ti wọn ri gba ni ike ororo onikilomita mẹẹẹdọgbọn, mejila, mọto aloku ogun, ọkada aloku meji, aṣọ aloku idi mẹrin, bata aloku mẹrindinlọgbọn,taya,iṣere ọmọde,baagi igbo to le ni igba,apo irẹsi, ẹgbẹrun meje,ọọdunrun ati mọkanla.

O sọ pe o ṣe ni laanu pe tirela Dangote ti wọn fi n ko simẹnti, ni wọn ri tawọn fayawọ fi ko irẹsi, ko to di pe ọwọ tẹ wọn.Bakan lo sọ pe ọwọ tẹ awọn meji,ti wọn fi ọkada wọn ko igbo, amọ ti wọn wa nibi ti wọn ti n gba itọju.
O tun waa lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ ọga wọn patapata,Ibrahim Hammed Ali atawọn alakoso ẹṣọ aṣọbode lori bi wọn tun ṣe fun wọn ni mọto Toyota Hillux mẹwaa, lati tun fi ranṣẹ wọn lọwọ.O ni owo tawọn pa si apo isuna ijọba laarin oṣu kan ati ọjọ meloo fẹẹ to miliọnu meji abọ naira. O wa pari ọrọ e pe awọn yoo tun maa tẹsiwaju lati gbogun tawọn onifayawọ titi ti wọn yoo fi dẹkun iṣẹ ibi wọn.

No comments:

Post a Comment

Pages