Awọn ọdọ Ikirun ni Akadir ni ki Oyetọla yan fawọn gẹgẹ bi ọba. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 7 December 2021

Awọn ọdọ Ikirun ni Akadir ni ki Oyetọla yan fawọn gẹgẹ bi ọba.


 

Ẹgbẹ ọdọ kan ti wọn jẹ Young Professionals Forum, YPF, ti rawọ ẹbẹ si Gomina ipinlẹ Ọsun, Ọgbẹni Adegboyega Oyeytọla, lati lo gbogbo agbara ẹ lati yanYunus Ọlalekan Akadir, gẹgẹ bi ọba Akinrun tilu Ikirun.

 

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ  aarẹ ẹgbẹ naa, Sulaiman Kilani ati akọwe ẹ, Sunday Owolabi fọwọ si ni wọn ti sọ pe Akadir, yii ni oludije tawọn ṣatilẹyin fun lati depo awọn babanla ẹ.

 

Wọn sọ pe tẹnu kọ, ti ẹgan si kọ pẹlu,  Oludije awọn yii lawọn ọdọ ilu gba gẹgẹ bi ẹni to kun oju oṣuwọn ninu gbogbo awọn to ti n jade wa, tawọn si nigbagbọ pe yoo ko ire ba ilu, yoo si tun mu idagbasoke ba a pẹlu.

 

Awọn ọdọ naa wa rọ Gomina lati gba ẹbẹ wọn, ko fi ọpa aṣẹ tuntun lọ ọkunrin naa lọwọ gẹgẹ bi ori ade ilu Ikirun. Bẹẹ ni wọn sọ pe awọn ko fẹẹ ko fi ọrọ naa falẹ mọ.

 

Atẹjade ọhun tun sọ pe’’ Awa ọdọ nigbagbọ  ninu Akadir lati di ọba Ikirun. O ṣetan lati lo ọrọ ẹ nidii okoowo lati fi mu idagbasoke ba ilu. A fẹẹ ki Gomina fun wa lẹni tawa mọ pe yoo mu itẹsiwaju rere ba wa’’.

 

Yunus Ọlalekan Akadir, Oyewọle, lo jẹ ọmọ ọmọ fun ọba Akirun, kọkanla, iyẹn Ọba Adekilekun Akadiri Oyewọle, to jẹ laaarin ọdun 1887 si 1917. 

 

Baba baba ẹ tun ni Akinrun keje, Ọba Oyewọle I. Ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdu, 1975 ni wọn bii.O si jẹ ọkan lara awọn to jade nileewe girama Coker Memorial High School, Ikirun. 

 

Oniṣowo to kun oju owo ni, to si lawọn ileeṣẹ kaakiri, to tun gba awọn eeyan ti wọn ṣiṣẹ labẹ ẹ. Bẹẹ lo si tun tidi iṣẹ to n ṣe yii rin iriajo lọọ si oke-okun. Oun ni ọga agba ati oludasilẹ ileeṣẹ Total Finishing Works Nig. Ltd.

 

Ọdun 2006, lo ṣegbeyawo pẹlu  Olori Ọmọtọla, ti Ọlọrun si fọmọ jinki wọn.

No comments:

Post a Comment

Pages