Jandor fẹgbẹ APC Eko silẹ bọ si PDP - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 7 December 2021

Jandor fẹgbẹ APC Eko silẹ bọ si PDP


Iyalẹnu lo jẹ ni opin ọsẹ to kọja yii nigba ti iroyin gba igboro pe alakoso" Lagos 4 Lagos "  to wa ninu ẹgbẹ APC,tẹlẹ, Abdul Azeez Adediran Ọlajide tọpọ mọ si Jandor, ti darapọ mọ PDP, tipinlẹ Eko.

 

Eto ọhun to waye ni Ikẹja, wọn ti gba Sẹnetọ Bukọla Saraki atawọn eeyan ẹ lalejo lọjọ naa. Ninu ọrọ ọkunrin naa lo ti sọ pe awọn kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lati fopin si baba sọ pe.

 

O ni bẹẹ ni iwa imunisin to gbilọ nipinlẹ Eko, eyi to ni ko faaye gba oludije mii in lati tẹ siwaju ninu eto oṣelu.O ni gẹgẹ bi ọmọ Eko tooto, awọn ko ni la oju silẹ ki talubọ kowọ, ayipada rere gbọdọ deba eto ijọba tiwa 'n' tiwa niluu Eko.

 

Ninu ọrọ ikinni kaabọ, Ọmọba-binrin Mama Jandor, dupẹ lọwọ Ogbẹni Jandor, fun igbesẹ akin, O ni opin gbọdọ deba eto oṣelu nipinlẹ Eko .

 

Bẹẹ lo ni oun ṣetan fun atilẹyin to peye fun ajọ " Lagos 4 Lagos. Ninu ọrọ Sẹnetọ Bukọla Ṣaraki, o sọ pe oro ipinlẹ Eko mu oun laya pupọ, nitori oun kawe nibẹ, ileeṣe oun si tun wa nibẹ pẹlu,iyawo oun omo Eko ni.

 

Saraki sọ pe awọn gba Jandor wọle sinu ẹgbẹ lẹyin agbeyẹwo to peye.

 

No comments:

Post a Comment

Pages