Wọn lọrọ Lekan to gun iyawo ẹ pa ni Ode- Rẹmọ ki i ṣoju lasan - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 6 November 2021

Wọn lọrọ Lekan to gun iyawo ẹ pa ni Ode- Rẹmọ ki i ṣoju lasan

  Arakunrin kan, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Ọlamilekan Mojiyagbe, ti wọn fẹsun kan pe o gun iyawo ẹ, Ṣeun Mojiyagbe, pa la gbọ pe yoo foju bale- ẹjọ laipẹ yii. Ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan an.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni wọn lọkunrin yii to n gbe Oke-Ọla, ni Ode_Rẹmọ, ti ilẹkun mọ iyawo ẹ ninu yara, to si lu u lalubami, to tun fi sisọọsi gun un yannayanna titi ti ẹmi fi bọ lara ẹ.

Abimbọla Oyeyẹmi, agbẹnusọ awọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, tun sọ pe ariwo ti obinrin ọhun wa lo ta sawọn ti wọn jọ n gbe laduugbo leti, ti wọn si sa gbogbo agbara lati jẹ ki ọkọ iyawo ṣilẹkun naa ṣugbọn ti ko da wọn lohun.

Awọn eeyan wọnyii ni wọn ta awọn ọlọpaa Ode-Rẹmọ, lolobo ti ọga wọn, CSP Ọlayẹmi Fagbohun, si ṣaaju awọn eeyan ẹ lọ sibẹ, nibi ti wọn ti ja ilẹkun ọhun tipatipa, nibẹ ni wọn si ti ba obinrin naa ninu agbata ẹjẹ.

Gbogbo agbara wọn lati doola ẹmi obinrin yii lo ja si pabo, nitori ki wọn to gbe de ọhun lo ti jẹ Ọlọrun nipe. Ṣugbọn nnkan tawọn eeyan to wa lagbegbe naa sọ ni pe ọrọ naa ki i ṣoju lasan.

Ni bayii, wọn ti gbe oku obinrin naa lọọ si mọṣuari, nigba ti CP Lanre Bankole, kọmiṣanna awọn ọlọpaa si ti  ni loju ẹsẹ ti wọn ba pari iwadii ni ki wọn gbe Lekan lọọ sile-ẹjọ.

 

No comments:

Post a Comment

Pages