Ọnarebu Ṣẹyẹ Ọladẹjọ, alukoro fẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Eko, ti sọ pe lakooko yii, ko tii si ẹni to kun oju oṣuwọn lati di aarẹ orileede yii ninu ibo to n bọ lọdun 2023, yatọ si Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, nitori awọn iriri to ti ni lori ijọba awarawa.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko
to n ba oniroyin wa sọrọ, o sọ pe bo tilẹ jẹ pe titi di akoko yii ọkunrin naa
ko tii sọ erongba ẹ sita lati fije ṣugbọn gbogbo awọn lawọn n rọ ọ lati jade
nitori oun nikan ni olugbala awọn mẹkunnu ti wọn ti n reti.
O sọ pe '' Bi a ba pe ori
akọni, a fi ida laalẹ, Baba wa ti ẹ darukọ yẹn, ẹni ti Ọlọrun da,ẹni ti Ọlọrun
gbe kalẹ fun wa lakooko yii, lati waa ṣe atunṣe ati afọmọ awọn nnkan to ti wọ
latẹyin wa. Ko to to akoko yii, oloore lo jẹ si ọpọlọpọ eeyan''.
''Irufẹ ẹda to jẹ lo mu ki
ọpọlọpọ awọn kan sọ pe idije aarẹ yii, awọn ṣetan lati sanjọ oore fun Baba wa
Bọla Ahmed Tinubu, ẹ ẹ tun waa rii pe ohun to tun waa faa taa fi n ri ọpọ awọn
eeyan kaakiri orileede yii ti wọn fi sọ pe a fi dandan ki wọn jade''.
''Baba wa titi di akoko yii,
ẹnikẹni ko le sọ pe, baba pe awọn lati waa gbaruku ti wọn, bi awa ọmọ ti wọn ti
ṣe loore ṣe n sọrọ to. Ẹ ẹ wa ri i pe oun to tọ, to si yẹ fun
ẹnikẹni to ba nifẹẹ ilu yii, ṣe nipa iriri ni tabi nipa awọn ohun meremere to
ti gbese lorileede yii tabi nipa iriri ijọba alagbada, ijọba tiwantiwa
lorileede yii, a bi nipa awọn to ti tipa baba jade lati ori aarẹ, igbakeji ẹ.
atawọn gomina''.
''Ohun to waa jẹ idojukọ
lorileede yii lakooko yii, ṣe ọrọ aje ni, okoowo,pẹlu oye to ni, ẹni to o to
gbangba sun lọyẹ ni wọn. Adura wa ni pe ninu ẹgbẹ APC, ki baba gba si wa lẹnu
lati dupo aarẹ, niwọngba to jẹ pe ohun eeyan ni ohun Ọlọrun''.
Bẹẹ lo tun sọ pe ''Lati ọjọ ti
alaye ti daye, bẹẹ ni, ọjọ ti ko ba si ni saaye mọ, wọn ni, wọn pe, ko nii
kuro,ọja ti awa n ta ni a ni fi epo ati iyọ si, wọn ja nile keji, ko kan mi, bi
a ba tun ni ki a daalẹ, ki a tun sa, wọn ni aifi agba fẹnikan, ko jẹ ki aye
gun.
''Ẹ ẹ ma jẹ ki a tan ara wa
jẹ, ika to ba tọ si imu lakooko ta a wa yii , lo yẹ ka fun, Baba wa Bọla Ahmed
Tinubu, awa ko ti ri eeyan kan to tọ lati dupo yatọ si wọn. Ko si ẹni ti nnkan
rere ko wuu,ṣugbọn ninu iyẹwu ẹ, o gbọdọ le gbe ara ẹ sori osuwọn.
''Awa o mọ ahesọ o, eyi tawa
mọ ni pe Baba wa Bọla Ahmed Tinubu lawa n tẹle, Ohun si ni a gbaruku ti, Ọlọrun
a fun wọn ni alaafia ati ẹmi gungun, wọn yoo depo naa.
Nipa wahala to n waye ninu ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Eko,
Ọladẹjọ sọ pe ''Se ẹ ri wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ o daa lori ailekoara ẹni
nijanu, laarin ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ, beeyan ba ṣe le finu findọ sọ pe oun fẹẹ
darapọ, yala ninu ẹgbẹ oṣelu, ijọsin tabi ẹlẹgbẹjẹgbẹ, itumọ to ni ni pe irufẹ
eeyan bẹẹ ṣetan lati huwa pọ ni ibamu ofin to jẹ ti ọmọ ẹgbẹ ati
ofin ti wọn ba fi le lẹ..
Bi a ba sọ pe o di ọmọ ẹgbẹ
naa tan, to wa ni iwa ko tẹ mi lọrun lo fẹẹ maa hu, o ku diẹ kaato,
ko si le ṣiṣẹ lawujọ eeyan, koda lawujọ ẹranko gan-an , gbogbo aye lo bọwọ fun
Kiniun oloola iju.
No comments:
Post a Comment