O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ lori agbekalẹ eto ere oṣupa, eyi to sọ pe yoo tubọ maa ran awọn eeyan leti nipa aṣa wa.
O sọ pe lojumọ to mọ lonii, akiyesi tawọn ṣe ni pe wọn ti gbe aṣa oyinbo gun ori oke tilẹ wa, fun apẹẹrẹ, o ni ko si ibọwọ mọ ninu ikinni wa, bẹẹ naa nipa imura, gbogbo awọn ipanle to n ṣẹlẹ lakooko yii, o ni nitori pe a ti gbe aṣa wọn wọnu aṣa wa.
Jamiu sọ pe ‘’Laye ọjọun, bi ọmọ ba lowo lọwọ, a gbọdọ wadii iru iṣẹ to n ṣe, bawo lo ṣe ri owo ko jọ, to fi rowo yẹn, ṣugbọn laye ode onii, ọmọ to ṣẹṣẹ jade, to n lo mọto oni miliọnu mẹfa naia, iṣẹ wo lo n ṣe, awa ni itiju, a maa n tọju orukọ wa nilẹ Yoruba, amọ nitori aṣa alaṣa, ti ko nii ṣe pẹlu bawo lo ṣe ri owo, bẹẹ la tun rii pe gbogbo awọn ti wọn fun ni ami ẹyẹ iyẹn awọọdu, lo jẹ pe ọpọ wọn lo n ṣe nnkan ti ko dara’’.
O tun sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ fun wa pe pupọ ninu awọn ọmọ ta a n bi lode iwoyi ni ko le sọ Yoruba, oyinbo ni, itiju nla lo si jẹ fun wa A ko ni kawọn ọmọ maa sọ gẹẹsi ṣugbọn ede tiwa n tiwa gbọdọ jẹ pataki.
Nigba to n sọ bi agbekalẹ ere oṣupa naa yoo ṣe ri, Ọmọọba Jamiu sọ pe awọn yoo maa lọ bawọn eeyan ni sakani bi ọba, baalẹ, awọn olori adugbo atawọn ijọba.
O ni lara amọran ti Ọmọọba Tajudeen Olusi, gbawọn lakooko tawọn lọọ ṣe abẹwo ni pe ki ijọba rii pe awọn ile igbalode ti wọn n kọ, ki wọn maa fi aye silẹ fawọn ọmọde lati maa ṣere oṣupa. O ni yoo maa mu irẹpọ wa ti ko si jẹ kawọn gbagbe awọn nnkan iṣẹbaye ilẹ Yoruba.
O ni ki i ṣe iwe, gbogbo ibi tawọn ba n lọ, awọn yoo ma pa itan, awọn yoo maa powe, wọn yoo ma gbawọn lalejo ni ọwọ irọlẹ, ẹnikan maa dari ẹ yoo pa itan fawọn yẹn.
Nnkan tawọn yoo si maa fayọ lawọn nnkan to jẹ mọ ilẹ Yoruba bii ibọwọ fun ni, itẹpa mọṣẹ, ifẹ, gbogbo ẹ lawọn fẹẹ da pada. Awọn yoo ma pa itan aye atijọ lati mu wa si iranti.
No comments:
Post a Comment