Ayẹyẹ ọdún àṣà Ìgánmọdẹ yóò wáyé nínú oṣù kejìlá - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 9 November 2021

Ayẹyẹ ọdún àṣà Ìgánmọdẹ yóò wáyé nínú oṣù kejìlá

Ọlọta tiluu Ọta, Ọba Adeyẹmi Ọbalalenge, ti rọ gbogbo tonile talejo to fi mọ awọn oni ileeṣẹ nlanla, lati ṣatilẹyin fun wọn fayẹyẹ aṣa Iganmọdẹ tọdun yii, eyi ti yoo waye ninu oṣu kejila, ọdun yii.

 

Kabiyesi sọrọ yii nibi ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn oniroyin fayẹyẹ ọhun, eyi to waye ni afin Ọlọta. O sọ pe ifọwọsowọpọ ati atilẹyin ijọba, ileeṣẹ nlanla ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ yoo tun jẹ ki ayẹyẹ naa ladun bii Ojude-Ọba ati Ọmọ Olowu.

 

O fikun ọrọ ẹ pe ayẹyẹ aṣa Iganmọdẹ ti wọn maa mn ṣe lọdọọdun yii jẹ iranti aṣa gbogbo ọmọ Ọtsa-Awori, to si tun maa n ko wọn pọ lati jọ wa ni irẹpọ. O ni Ọta jẹ ibi to tan kaa kaakiri ipinlẹ bẹẹ tawọn ileṣẹ nlanla tun wa pẹlu.

 

Ọbalanlẹgẹ tun ṣalaye pe awọn ṣayẹyẹ Iganmọdẹ yii lati fi ṣeranti awọn babanla wọn to jẹ jagunjagun fawọn ipa ti wọn ti ko, nitori idi eyi lo ṣe rọ gbogbo ọmọ bibi ilu naa atawọn alejo lati wa fun ajọyọ ọdun naa.

 

NInu ọrọ Aarẹ Ayọdele Bankọle,  to jẹ alaga igbimọ ayẹyẹ ọhun, lo ti sọ pe ayẹyẹ tọdun yii yoo tun larinrin ju ti atẹyinwa lọ, nitori lara awọn eto tawọn la silẹ ni ẹdawo, igbekalẹ ati eto jẹ eyi to jẹ koko julọ.

 

O sọ pe ohun ti ayẹyẹ aṣa Iganmọdẹ da le lori ni aṣiwaju, akinkanju, iṣọkan ati lati jọ ṣiṣẹ pọ.Bẹẹ lo ni o tun mu igbega ba aṣa ati iṣe gbogbo ilẹ Awori. Laaari ọjọ kẹtala si ọjọ kọckandinlogun, oṣu kejila, ọdun yii lo sọ pe ayẹyẹ ọhun yoo waye.

 

Adura awọn oṣugbo lo sọ pe wọn yoo fi bẹrẹ, bakan naa ni ayẹwo lọfẹẹ, lilọ sile awọn ọmọ ti ko niya ni Ijamido, naa wa lara reto wọn. Awọn eto mii in tun ni apero laaarin awọn ọdọ, Pambabari ẹ ni aṣekagba nibi tawọn alejo Pataki ti wọn fiwee pe yoo ti wa yẹ wọn si bẹẹ ni Kabiyesi yoo tun foye da awọn kan lọla.

Capt;

No comments:

Post a Comment

Pages