Ọla ni Ṣeun Abolurin siifu difẹnsi yoo gba ami ẹyẹ alukoko to dara julọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 9 November 2021

Ọla ni Ṣeun Abolurin siifu difẹnsi yoo gba ami ẹyẹ alukoko to dara julọ



Gbogbo eto lo ti to bayii fun ayẹyẹ ami ẹyẹ, iyẹn awọọdu, ti wọn fẹẹ fun Ọgbẹni Oluwaseun Abolurin, agbẹnusọ fawọn ajọ alaabo ilu, siifu difẹnsi, tipinlẹ Eko, gẹgẹ bi alukoro to dara ju lọ fọdun 2021.

Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ wa lọwọ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni ayẹyẹ naa yoo waye ni  NECA House, Sẹkiteriati, Alausa, niluu Eko, bẹrẹ ni deede aago mẹwaa aarọ.

Nitori awọn ipa ti ọkunrin naa ti ko nipa iroyin laarin awọn alaabo yooku ẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ, ni wọn ṣe sọ pe oun lo tọ to si yẹ fami ẹyẹ naa, ko tun le jẹ iwuri nla lati le tẹsiwaju nipa iṣẹ to yan an laayo.

 Ẹgbẹ kan to n gbe  iroyin jade nipa aabo lori ẹrọ ayelujara iyẹn National Association of Online Security News Publishers, ni wọn sọ pe o ṣagbatẹru eto naa  


No comments:

Post a Comment

Pages