Gbajumọ oṣere onitiata nni, Alaaji Fatai Adetayọ, tọpọ mọ si Fatai Oodua, tawọn kan tun pe ni Lalude, fẹẹ ṣayẹyẹ aadọta ọdun, to bẹrẹ iṣẹ tiata, eyi ti yoo waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yiii niluu Ibadan.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni oun fẹẹ fi ayẹyẹ naa dupẹ lọwọ Ọlọrun, fun idasi ẹ latigba to ti bẹrẹ ere ọhun. Gbọngan Gẹnẹsis, to wa ni Challenge, ni Ibadan lo sọ pe ayẹyẹ naa yoo ti waye bẹrẹ ni deede aago mejila ọsan.
Oṣere to saaba maa n ṣere oloogun lọpọ fiimu to n jade tun fikun ọrọ e pe aṣọ ankara ẹgbẹjọda lawọn to ba fẹẹ wa sibi ayẹyẹ ọhun yoo wọ lati wọle ati pe ẹgbẹrun mẹrin lọpa mẹrin aṣọ naa fẹni to ba fẹẹ ra.
Gbajumọ olorin fuji nni, Taye Currency ni yoo wa ṣere fawọn eeyan lọjọ yii nigba ti Alaaji Gboyega Lawal ni yoo dari eto.
Lara awọn ọba alaye ti wọn reti lọjọ naa ni Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta, Iku Baba Yeye.Ọọni tilu Ile-,Ifẹ, Ọba Adeyẹyẹ Ẹnitan Ogunwusi, Olubadan tiluu Ibadan, Ọba Saliu Adetunji Akanmu.Nigba ti King Sunny Ade, yoo jẹ baba ọjọ naa.
No comments:
Post a Comment