Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ́kànlá wọlé síléèwé gíga yunifásítì NOUN - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 6 November 2021

Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ́kànlá wọlé síléèwé gíga yunifásítì NOUN

 


Awọn ẹlẹwọn mọkanla, ti ọgba ẹwọn to wa ni Ibara, niluu Abẹokuta, ni wọn ti lafaani lati kawe nileewe giga yunifasiti  National Open University of Nigeria,iyẹn NOUN, nigba ti wọn ṣayẹyẹ igbaniwọle fun wọn.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọgbẹni Victor Oyeleke, agbẹnusọ fun ọgba ẹwọn ọhun fi sita, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, ni wọn ṣayẹyẹ igbaniwọle fawọn eeyan ọhun pẹlu oriṣiriṣi ẹkọ ti wọn fẹẹ kọ lọhun.

Igba kẹta ree ta a gbọ wọn yoo ṣayẹyẹ igbaniwọle fawọn ẹlẹwọn ni abẹ ileewe giga NOUN. Dokita Ṣẹgun Adenuga, to jẹ alakoso nile ikawe wọn ni Abẹokuta, lo gba awọn eeyan ọhun wọle lorukọ ọga ileewe yii, Ọjọgbọn Olufẹmi Peter.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ naa. Haliru Nabba, ọga agba patapata fọgba ẹwọn lorileede yii, ẹni ti Abdulrasheed Alimi, to jẹ ọga wọn nipinlẹ Ogun, ṣoju fun lo ti rọ awọn akẹkọọ ti wọn gba wọle lati kẹkọọ naa pe ki wọn lo anfaani yii fun pataki ni igbe aye wọn.

O ni igbesẹ ti wọn yii jẹ lara eyi tawọn to n ṣakoso ọgba ẹwọn lo lati le jẹ ki wọn da wọn pada si awujọ. Pẹlu idaniloju pe wọn yoo tẹsiwaju lati maa ṣatilẹyin fun wọn nipa eto ẹkọ. O ni awọn bi ẹgbẹrun mẹta awọn ẹlẹwọn ni wọn ti n jafaani iru eto yii nileewe giga NOUN atawọn ileewe giga yunifasiti mii in, ti wọn si jọ n ṣe ajọṣepọ.

Nabba wa gboriyin fun aarẹ Muhammadu  Buhari, fun atilẹyin ẹ lori eto yii fun idagbasoke lawujọ.

Ninu ọrọ ti ọga agba ileewe ọhun, Ọjọgbọn Olufemi Peters, ẹni ti Dokita ẹgun Adenuga, ṣoju fun un lo ti mu da awọn ẹlẹwọn naa loju pe ileewe naa yoo sa gbogbo agbara wọn lati le jẹ ki ẹkọ naa rọrun fun wọn.

O wa rọ wọn lati ma ṣe doju ti ileewe naa nipa ihuwasi wọn. O wa dupẹ lọwọ awọn alaṣẹ ileewe ọhun fun ifọwọsowọpọ wọn lori ki awọn ẹlẹwọn le mọ pe ibi ti wọn wa yii ki ṣe opin aye wọn.

Ayẹyẹ igbaniwọle yii lo jẹ ki ẹlẹwọn to n kawe fun oriṣiriṣi ẹkọ jẹ mọkanlelọgọta lati ileewe ọhun, nigba ti meji si tun tẹsiwaju fun masta ninu wọn.

 

No comments:

Post a Comment

Pages