Ajalu nla lo ja lu ẹgbẹ awọn oniroyin nipinlẹ Ogun, nigba ti alaga wọn, Ọgbẹni Oluṣọji Amosu,, jade laye. Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọgbẹni Kunle Ewuoso, akọwe ẹgbẹ naa fi sita, laaarọ yii lo sọ pe iku pa oju ọkunrin naa de lẹyin aisan ranpẹ..
Bẹẹ lo tun sọ pe wọn yoo ṣi iwe ibamikẹdun agba oniroyin ọhun si iwe iroyin bẹrẹ lati ọla lọ, ti wọn yoo si kede bi eto isinku yoo ṣe lọ laipẹ. Ẹkunrẹrẹ iroyin nipa ọkunrin naa n bọ laipẹ.
No comments:
Post a Comment