Alake fẹ́ẹ́ fi Ṣólebọ̀ ọ̀gá àwọn ọlọ́kadà ROMO joyè Bọ̀rọ̀kìní ilẹ̀ Ẹ̀gbá - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 13 November 2021

Alake fẹ́ẹ́ fi Ṣólebọ̀ ọ̀gá àwọn ọlọ́kadà ROMO joyè Bọ̀rọ̀kìní ilẹ̀ Ẹ̀gbá



Lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii ni Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ yoo fi Oloye Rasaki Oluṣọla Ṣotayọ, tọpọ mọ si Ṣolebọ, alaga fẹgbẹ awọn ọlọkada ROMO, nipinlẹ Ogun, joye Bọrọkini ilẹ Ẹgba.

 

Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sọwọ si wa, afin Alake, to wa ni Ake, niluu Abẹokuta, ni ifinijoye naa yoo waye, nibi ti wọn yoo si tun ti fun un ni ọpa aṣẹ ati iwe ẹri lọjọ naa.

Wọn ni awọn ipa ti ọkunrin naa ti ko lawujọ ni wọn ṣe fun un loye ọhun.

 

Bẹẹ la tun gbọ pe ọkunrin naa tun ti wa nidii iṣẹ igbokegbodo lati nnkan bii ogun ọdun sẹyin, to si jẹ pe o ti tipasẹ ẹ mu ki ọrọ aje gbooro si nipinlẹ Ogun. Wọn awọn nnkan idagbasoke to ti mu ba ipinlẹ Ogun, tun ku awọn nnkan ti wọn wo mọ ọn lara.

No comments:

Post a Comment

Pages